1
Romu 3:23-24
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Romu 3:23-24
2
Romu 3:22
Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni.
Ṣàwárí Romu 3:22
3
Romu 3:25-26
Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.
Ṣàwárí Romu 3:25-26
4
Romu 3:20
Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.
Ṣàwárí Romu 3:20
5
Romu 3:10-12
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run. Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”
Ṣàwárí Romu 3:10-12
6
Romu 3:28
Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.
Ṣàwárí Romu 3:28
7
Romu 3:4
Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”
Ṣàwárí Romu 3:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò