KỌRINTI KINNI 15
15
Ajinde Kristi
1Ará, mo fẹ́ ran yín létí ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, tí ẹ gbà, tí ẹ sì bá dúró. 2Nípa ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là, tí ẹ bá dì mọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ asán ni igbagbọ yín.
3Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.#Ais 53:5-12 4Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.#O. Daf 16:8-10; Mat 12:40 A. Apo 2:24-32 5Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.#a Luk 24:34; b Mat 28:16-17; Mak 16:14; Luk 24:36; Joh 20:19 6Lẹ́yìn náà ó tún fara han ẹẹdẹgbẹta (500) àwọn onigbagbọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọpọlọpọ ninu wọn wà títí di ìsinsìnyìí, ṣugbọn àwọn mìíràn ti kú. 7Lẹ́yìn náà, ó fara han Jakọbu, ó sì tún fara han gbogbo àwọn aposteli.
8Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín gbogbo wọn, ó wá farahàn mí, èmi tí mo dàbí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé.#A. Apo 9:3-6 9Nítorí èmi ni mo kéré jùlọ ninu àwọn aposteli. N kò tilẹ̀ yẹ ní ẹni tí wọn ìbá máa pè ní aposteli, nítorí pé mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọrun.#A. Apo 8:3 10Ṣugbọn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí kò sì jẹ́ lásán lórí mí, nítorí mo ṣe akitiyan ju gbogbo àwọn aposteli yòókù lọ. Ṣugbọn kì í ṣe èmi tìkara mi, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi ni. 11Nítorí náà, ìbáà ṣe èmi ni, tabi àwọn aposteli yòókù, bákan náà ni iwaasu wa, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí ẹ gbàgbọ́.
Ajinde Òkú
12Nígbà tí ó jẹ́ pé, à ń kéde pé Kristi jinde kúrò ninu òkú, báwo ni àwọn kan ninu yín ṣe wá ń wí pé kò sí ajinde òkú? 13Bí kò bá sí ajinde òkú, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. 14Bí a kò bá jí Kristi dìde ninu òkú, a jẹ́ pé asán ni iwaasu wa, asán sì ni igbagbọ yín. 15Tí ó bá jẹ́ pé a kò jí àwọn òkú dìde, a tún jẹ́ pé a purọ́ mọ́ Ọlọrun, nítorí a jẹ́rìí pé ó jí Kristi dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jí i dìde. 16Nítorí pé bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. 17Bí a kò bá sì jí Kristi dìde, a jẹ́ pé lásán ni igbagbọ yín, ẹ sì wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín sibẹ. 18Tí ó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn onigbagbọ tí wọ́n ti kú ti ṣègbé! 19Tí ó bá jẹ́ pé ninu ayé yìí nìkan ni a ní ìrètí ninu Kristi, àwa ni ẹni tí àwọn eniyan ìbá máa káàánú jùlọ!
20Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú. 21Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé. 22Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè. 23Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde. 24Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé, lẹ́yìn tí ó bá ti dá ìjọba pada fún Ọlọrun Baba, tí ó sì ti pa gbogbo àṣẹ, ọlá ati agbára run. 25Nítorí ó níláti jọba títí Ọlọrun yóo fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí ìkáwọ́ rẹ̀.#O. Daf 110:1 26Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí yóo parun. 27Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ó ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nígbà tí ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan ni ó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀,” ó dájú pé ẹnìkan ni kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀: ẹni náà sì ni Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ Kristi.#O. Daf 8:6 28Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnrarẹ̀ yóo wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọrun lè jẹ́ olórí ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.
29Ó tún ku nǹkankan! Nítorí kí ni àwọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, kí ni ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn?#2 Makab 12:44 30Àwa náà ńkọ́? Nítorí kí ni a ṣe ń fi ẹ̀mí wa wéwu nígbà gbogbo? 31Lojoojumọ ni mò ń kú! Ará, mo fi ìgbéraga tí mo ní ninu yín búra, àní èyí tí mo ní ninu Kristi Jesu Oluwa wa.#Ais 22:13 32Bí mo bá tìtorí iyì eniyan bá ẹranko jà ní Efesu, anfaani wo ni ó ṣe fún mi? Bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, bí wọ́n ti máa ń wí, wọn á ní:
“Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, kí á máa mu,
nítorí ọ̀la ni a óo kú.”
33Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́. 34Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni.
Ara Lẹ́yìn Ajinde
35Ṣugbọn ẹnìkan lè bèèrè pé, “Báwo ni a óo ti ṣe jí àwọn òkú dìde? Irú ara wo ni wọn óo ní?” 36Ìwọ òmùgọ̀ yìí! Bí irúgbìn tí a bá gbìn kò bá kọ́ kú, kò lè hù. 37Ohun tí ó bá hù kì í rí bí ohun tí a gbìn ti rí, nítorí pé irúgbìn lásán ni, ìbáà ṣe àgbàdo tabi àwọn ohun ọ̀gbìn yòókù. 38Ọlọrun ni ó ń fún un ní ara tí ó bá fẹ́, a fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀.
39Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe oríṣìí kan náà. Ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara eniyan, ọ̀tọ̀ ni ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ni ti ẹyẹ, ọ̀tọ̀ ni ti ẹja.
40Àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tí ń fò lófuurufú wà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti orí ilẹ̀ wà. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà ti àwọn tí ń fò lófuurufú. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà àwọn ti orí ilẹ̀. 41Ọ̀tọ̀ ni ẹwà oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ ni ti àwọn ìràwọ̀, ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ara wọn ní ẹwà.
42Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà ajinde àwọn òkú. A gbìn ín ní ara tíí díbàjẹ́; a jí i dìde ní ara tí kì í díbàjẹ́. 43A gbìn ín ní àìlọ́lá; a jí i dìde pẹlu ògo. A gbìn ín pẹlu àìlera: a jí i dìde pẹlu agbára. 44A gbìn ín pẹlu ara ti ẹ̀dá, a jí i dìde ní ara ti ẹ̀mí. Bí ara ti ẹ̀dá ti wà, bẹ́ẹ̀ ni ti ẹ̀mí wà. 45Ó wà ninu àkọsílẹ̀ pé, “Adamu, ọkunrin àkọ́kọ́ di alààyè;” ṣugbọn Adamu ìkẹyìn jẹ́ ẹ̀mí tí ó ń sọ eniyan di alààyè.#Jẹn 2:7 46Kì í ṣe ẹni ti ẹ̀mí ni ó kọ́kọ́ wà bíkòṣe ẹni ti ara, lẹ́yìn náà ni ẹni ti ẹ̀mí. 47Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá. 48Bí ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí a fi erùpẹ̀ dá rí. Bí ẹni tí ó wá láti ọ̀run ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ti ọ̀run rí. 49Bí a ti gbé àwòrán ti ẹni erùpẹ̀ wọ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé àwòrán ti ẹni ọ̀run wọ̀.
50Ará, ohun tí mò ń sọ ni pé ẹran-ara ati ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọrun, ati pé ohun tíí bàjẹ́ kò lè jogún ohun tí kì í bàjẹ́.
51-52Ẹ fetí sílẹ̀! Nǹkan àṣírí ni n óo sọ fun yín. Gbogbo wa kọ́ ni a óo kú, ṣugbọn nígbà tí fèrè ìkẹyìn bá dún, gbogbo wa ni a óo pa lára dà, kíá, bí ìgbà tí eniyan bá ṣẹ́jú. Nítorí fèrè yóo dún, a óo wá jí àwọn òkú dìde pẹlu ara tí kì í bàjẹ́, àwa náà yóo wá yipada.#1 Tẹs 4:15-17 53Nítorí ara tíí bàjẹ́ yìí níláti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀; ara tí yóo kú yìí níláti gbé ara tí kì í kú wọ̀. 54Nígbà tí ara tíí bàjẹ́ bá ti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀ tán, tí ara tí yóo kú bá sì ti gbé ara tí kì í kú wọ̀, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ tí a ti kọ sílẹ̀ yóo wá ṣẹ pé,
“A ti gbé ikú mì,
a sì ti ṣẹgun.”#Ais 25:8
55“Ikú, oró rẹ dà?
Isà òkú, ìṣẹ́gun rẹ dà?”#Hos 13:14
56Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó fún ikú lóró. Òfin ni ó fún ẹ̀ṣẹ̀ lágbára. 57Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi.
58Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ dúró gbọningbọnin, láì yẹsẹ̀. Ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo. Ẹ kúkú ti mọ̀ pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe níbi iṣẹ́ Oluwa kò ní jẹ́ lásán.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KỌRINTI KINNI 15: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: