KỌRINTI KINNI 6
6
Onigbagbọ Ń Pe Ara Wọn Lẹ́jọ́ Níwájú Àwọn Alaigbagbọ
1Kí ló dé tí ẹni tí ó bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkejì rẹ̀ fi ń gbé ẹjọ́ lọ siwaju àwọn alaigbagbọ? 2Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ ayé? Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ óo ṣe ìdájọ́ ayé, ó ti wá jẹ́ tí ẹ kò fi lè ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó kéré jùlọ? 3Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwa onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli! Mélòó-mélòó wá ni àwọn nǹkan ti ayé yìí? 4Bí ẹ bá ní ẹ̀sùn nípa nǹkan ti ayé, kí ló dé ti ẹ fi ń pe àwọn alaigbagbọ tí kò lẹ́nu ninu ìjọ láti máa jókòó lórí ọ̀rọ̀ yín? 5Kí ojú baà lè tì yín ni mo fi ń sọ̀rọ̀ báyìí! Ṣé kò wá sí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó gbọ́n tó láti dá ẹjọ́ fún ẹnìkan ati arakunrin rẹ̀ ni? 6Dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, onigbagbọ ń pe onigbagbọ lẹ́jọ́ níwájú àwọn alaigbagbọ!
7Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ? 8Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ! 9Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin; 10àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun. 11Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.
Ẹ Fi Ara Yín Yin Ọlọrun
12Ẹnìkan lè sọ pé, “Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí o lè ṣe ni yóo ṣe ọ́ ní anfaani. Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe, ṣugbọn n kò ní jẹ́ kí ohunkohun jọba lé mi lórí.#1 Kọr 10:23 13Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ. Ṣugbọn ati oúnjẹ ati ikùn ni Ọlọrun yóo parun. Ara kò wà fún ṣíṣe àgbèrè bíkòṣe pé kí á lò ó fún Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wà fún ara. 14Bí Ọlọrun ti jí Oluwa dìde kúrò ninu òkú, bẹ́ẹ̀ ní yóo jí àwa náà pẹlu agbára rẹ̀.
15Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni àwọn ẹ̀yà ara yín jẹ́? Ṣé kí a wá sọ ẹ̀yà ara Kristi di ẹ̀yà ara àgbèrè ni? Ọlọrun má jẹ̀ẹ́! 16Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá alágbèrè lòpọ̀ ti di ara kan pẹlu rẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ pé. “Àwọn mejeeji yóo di ara kan.”#Jẹn 2:24 17Ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ìdàpọ̀ pẹlu Oluwa di ọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ẹ̀mí.
18Ẹ sá fún ìwà àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan lè máa dá kò kan ara olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkararẹ̀. 19Àbí, ẹ kò mọ̀ pé ara yín ni ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà ninu yín, tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Ati pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ni ara yín?#1 Kọr 3:16; 2 Kọr 6:16. 20Iyebíye ni Ọlọrun rà yín, nítorí náà, ẹ fi ara yín yin Ọlọrun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KỌRINTI KINNI 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: