ÀWỌN ỌBA KINNI 22
22
Wolii Mikaaya Kìlọ̀ fún Ahabu
(2Kron 18:2-27)
1Fún ọdún mẹta lẹ́yìn èyí, kò sí ogun rárá láàrin ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Siria. 2Nígbà tí ó di ọdún kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda, lọ bẹ Ahabu, ọba Israẹli wò.
3Ahabu bi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa ni a ni ìlú Ramoti Gileadi? A kò sì ṣe ohunkohun láti gbà á pada lọ́wọ́ ọba Siria.” 4Ó bi Jehoṣafati pé, “Ṣé o óo bá mi lọ, kí á jọ lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi?”
Jehoṣafati bá dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ti yá ọ, ó yá mi. Tìrẹ ni àwọn eniyan mi, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹṣin mi pẹlu.” 5Jehoṣafati fi ṣugbọn kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ OLUWA ná.”
6Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ?
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.”
7Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè pé, “Ṣé kò tún sí wolii OLUWA mìíràn mọ́, tí a lè wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀?”
8Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.”
Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”
9Ahabu bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààfin pé kí ó lọ pe Mikaaya, ọmọ Imila, wá kíákíá.
10Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 11Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.” 12Nǹkan kan náà ni gbogbo àwọn wolii yòókù ń wí, gbogbo wọn ní kí Ahabu lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, wọ́n ní OLUWA yóo fún un ní ìṣẹ́gun.
13Iranṣẹ tí ọba rán lọ pe Mikaaya wí fún un pé, “Gbogbo àwọn wolii yòókù ni wọ́n ti fi ohùn ṣọ̀kan tí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún ọba, ìwọ náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ó bá tiwọn mu, kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere.”
14Ṣugbọn Mikaaya dáhùn pé, “OLUWA alààyè, ń gbọ́! Ohun tí OLUWA bá wí fún mi ni n óo sọ.”
15Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọba, ọba bi í pé, “Mikaaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi ni, àbí kí á má lọ?”
Mikaaya dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.”
16Ṣugbọn Ahabu tún bi í pé, “Ìgbà mélòó ni n óo sọ fún ọ pé, nígbà tí o bá sọ̀rọ̀ fún mi ní orúkọ OLUWA, kí o máa sọ òtítọ́ fún mi?”
17Mikaaya bá dáhùn pé, “Mo rí àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo orí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA sì wí pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí, kí olukuluku wọn pada lọ sí ilé ní alaafia.’ ”#Nọm 27:17; Mat 9:36; Mak 6:34
18Ahabu bá wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi burúkú?”
19Mikaaya dáhùn pé, “Ó dára, fetí sílẹ̀, kí o gbọ́ ohun tí OLUWA wí, mo rí i tí OLUWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ati tòsì,#Job 1:6; Ais 6:1. 20OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu jẹ, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi kí wọ́n sì pa á níbẹ̀?’ Bí angẹli kan ti ń sọ ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni òmíràn sì ń sọ nǹkan mìíràn. 21Ẹ̀mí kan bá jáde siwaju OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tàn án jẹ.’ 22OLUWA bá bi í pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o óo dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo mú kí gbogbo àwọn wolii Ahabu purọ́ fún un.’ OLUWA bá dáhùn pé, ‘Lọ tàn án jẹ, o óo ṣe àṣeyọrí.’
23“Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, OLUWA ni ó jẹ́ kí àwọn wolii wọnyi máa purọ́ fún ọ, nítorí pé ó ti pinnu láti jẹ́ kí ibi bá ọ.”
24Sedekaya wolii, ọmọ Kenaana bá súnmọ́ Mikaaya, ó gbá a létí, ó ní, “Ọ̀nà wo ni Ẹ̀mí OLUWA gbà fi mí sílẹ̀, tí ó sì ń bá ìwọ sọ̀rọ̀.”
25Mikaaya bá dá a lóhùn pé, “O óo rí i nígbà tí ó bá di ọjọ́ náà, tí o bá sá wọ yàrá inú patapata lọ, láti fi ara pamọ́.”
26Ọba Israẹli bá dáhùn pé, “Ẹ mú Mikaaya pada lọ fún Amoni, gomina ìlú yìí, ati Joaṣi ọmọ ọba. 27Ẹ ní, èmi ọba ni mo ní kí ẹ sọ fún wọn pé, kí wọ́n jù ú sinu ẹ̀wọ̀n, kí wọn sì máa fún un ní àkàrà lásán ati omi, títí tí n óo fi pada dé ní alaafia.”
28Mikaaya bá dáhùn pé, “Bí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ló gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó ní, “Gbogbo eniyan, ṣé ẹ gbọ́ ohun tí mo wí?”
Ikú Ahabu
(2Kron 18:28-34)
29Ahabu, ọba Israẹli, ati Jehoṣafati, ọba Juda, bá lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi. 30Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sí ojú ogun yìí, n óo paradà, kí ẹnikẹ́ni má baà dá mi mọ̀. Ṣugbọn ìwọ, wọ aṣọ oyè rẹ.” Ahabu, ọba Israẹli, bá paradà, ó sì lọ sójú ogun.
31Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ mejeejilelọgbọn, pé kí wọ́n má lépa ẹnikẹ́ni lójú ogun, àfi ọba Israẹli nìkan. 32Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati ọba, wọ́n ní, “Dájúdájú ọba Israẹli nìyí.” Wọ́n bá yipada láti bá a jà; ṣugbọn Jehoṣafati kígbe. 33Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe òun ni ọba Israẹli, wọ́n bá pada lẹ́yìn rẹ̀. 34Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́.
35Ogun gbóná gidigidi ní ọjọ́ náà. Ọwọ́ ni wọ́n fi ti ọba Ahabu ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà, tí ó sì kọjú sí àwọn ará Siria. Nígbà tí yóo sì fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn láti ojú ọgbẹ́ rẹ̀ sì ti dà sí ìsàlẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun náà. 36Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, wọ́n kéde fún gbogbo àwọn ọmọ ogun pé, “Kí olukuluku pada sí agbègbè rẹ̀! Kí kaluku kọrí sí ìlú rẹ̀!”
37Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ọba ṣe kú; wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí Samaria, wọ́n sì sin ín sibẹ. 38Wọ́n lọ fọ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní adágún Samaria, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì lọ wẹ̀ ninu adágún náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóo rí.
39Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Ahabu ọba ṣe, ati àkọsílẹ̀ bí ó ṣe fi eyín erin ṣe iṣẹ́ ọnà sí ààfin rẹ̀, ati ti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. 40Lẹ́yìn tí òun kú ni Ahasaya ọmọ rẹ̀ gun orí oyè.
Jehoṣafati, Ọba Juda
(2Kron 20:31–21:1)
41Ní ọdún kẹrin tí Ahabu, ọba Israẹli, gun orí oyè, ni Jehoṣafati, ọmọ Asa, gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda. 42Ọmọ ọdún marundinlogoji ni Jehoṣafati nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹẹdọgbọn. Asuba ọmọ Ṣilihi ni ìyá rẹ̀. 43Ohun tí ó dára lójú OLUWA, tí Asa baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe; ṣugbọn kò wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n wà káàkiri. Àwọn eniyan tún ń rúbọ, wọ́n sì tún ń sun turari níbẹ̀. 44Jehoṣafati bá ọba Israẹli ṣọ̀rẹ́, alaafia sì wà láàrin wọn.
45Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe, gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ati gbogbo ogun tí ó jà, wà ninu àkọsílẹ̀ Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 46Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí ó kù ní ilé àwọn oriṣa láti àkókò Asa, baba rẹ̀, ni ó parun ní ilẹ̀ náà.
47Kò sí ọba ní ilẹ̀ Edomu. Adelé ọba kan ní ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.
48Jehoṣafati ọba kan àwọn ọkọ̀ ojú omi bíi ti ìlú Taṣiṣi, láti kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ofiri láti lọ wá wúrà. Ṣugbọn wọn kò lè lọ nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà bàjẹ́ ní Esiongeberi. 49Ahasaya ọba Israẹli, ọmọ Ahabu, ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé kí àwọn eniyan òun bá àwọn eniyan rẹ̀ tu ọkọ̀ lọ, ṣugbọn Jehoṣafati kò gbà.
50Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.
Ahasaya, Ọba Israẹli
51Ní ọdún kẹtadinlogun tí Jehoṣafati, ọba Juda, gun orí oyè ni Ahasaya, ọmọ Ahabu, gun orí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba ní Samaria fún ọdún meji. 52Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú Ahabu, baba rẹ̀, ati ti Jesebẹli, ìyá rẹ̀, ati ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, àwọn tí wọ́n jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀. 53Ó bọ oriṣa Baali, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú ní gbogbo ọ̀nà bí baba rẹ̀ ti ṣe.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ỌBA KINNI 22: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapistaging.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fyo.png&w=128&q=75)
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapistaging.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fen.png&w=128&q=75)