SAMUẸLI KINNI 1
1
Elikana ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ìlú Ṣilo
1Ọkunrin kan wà ninu ẹ̀yà Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikana, ará Ramataimu-sofimu, ní agbègbè olókè Efuraimu. Orúkọ baba rẹ̀ ni Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, láti ìdílé Sufu, ará Efuraimu. 2Iyawo meji ni Elikana yìí ní. Ọ̀kan ń jẹ́ Hana, ekeji sì ń jẹ́ Penina. Penina bímọ, ṣugbọn Hana kò bí. 3Ní ọdọọdún ni Elikana máa ń ti Ramataimu-sofimu lọ sí Ṣilo láti lọ sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati láti rúbọ sí i. Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli, ni alufaa OLUWA níbẹ̀. 4Ní ọjọ́ tí Elikana bá rú ẹbọ rẹ̀, a máa fún Penina ní ìdá kan ninu nǹkan tí ó bá fi rúbọ, a sì máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin ní ìdá kọ̀ọ̀kan. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ràn Hana, sibẹ ìdá kan ní í máa ń fún un, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí. 6Penina, orogún Hana, a máa fín in níràn gidigidi, kí ó baà lè mú un bínú, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí. 7Ní ọdọọdún tí wọ́n bá ti lọ sí ilé OLUWA ni Penina máa ń mú Hana bínú tóbẹ́ẹ̀ tí Hana fi máa ń sọkún, tí kò sì ní jẹun. 8Ọkọ rẹ̀ a máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, a máa bi í pé, “Kí ní ń pa ọ́ lẹ́kún? Kí ló dé tí o kò jẹun? Kí ní ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ṣé n kò wá ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ ni?”
Hana ati Eli
9Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA. 10Inú Hana bàjẹ́ gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura sí OLUWA, ó sì ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. 11Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.”#Nọm 6:5
12Bí Hana ti ń gbadura sí OLUWA, Eli ń wo ẹnu rẹ̀. 13Hana ń gbadura ninu ọkàn rẹ̀, kìkì ètè rẹ̀ nìkan ní ń mì, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Nítorí náà, Eli rò pé ó ti mu ọtí yó ni. 14Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “O óo ti mu ọtí waini pẹ́ tó? Sinmi ọtí mímu.”
15Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA. 16Má rò pé ọ̀kan ninu àwọn oníranù obinrin ni mí. Ninu ìbànújẹ́ ńlá ati àníyàn ni mò ń gbadura yìí.”
17Eli bá dá a lóhùn, ó ní, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun Israẹli yóo fún ọ ní ohun tí ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.”
18Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́.
Ìbí Samuẹli ati Ìyàsímímọ́ Rẹ̀
19Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀. 20Hana lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọmọ náà ní Samuẹli, ó ní, “Títọrọ ni mo tọrọ rẹ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”
21Nígbà tí ó yá, àkókò tó fún Elikana ati ìdílé rẹ̀ láti lọ sí Ṣilo, láti lọ rú ẹbọ ọdọọdún, kí Elikana sì san ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ fún OLUWA. 22Ṣugbọn Hana kò bá wọn lọ. Ó wí fún ọkọ rẹ̀ pé, “Bí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọ yìí ni n óo mú un lọ sí ilé OLUWA, níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí ọjọ́ ayé rẹ̀.”
23Elikana dá a lóhùn pé, “Ṣe bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ. Dúró ní ilé, títí tí o óo fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí OLUWA jẹ́ kí o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ.” Hana bá dúró ní ilé, ó ń tọ́jú ọmọ náà.
24Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà. 25Lẹ́yìn tí wọ́n ti pa akọ mààlúù náà tán, wọ́n mú Samuẹli tọ Eli lọ. 26Hana bèèrè lọ́wọ́ Eli pé, “Oluwa mi, ǹjẹ́ o ranti mi mọ́? Èmi ni obinrin tí o rí níjelòó, tí mo dúró níhìn-ín níwájú rẹ, tí mò ń gbadura sí OLUWA. 27Ọmọ yìí ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ OLUWA, ó sì fún mi ní ohun tí mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. 28Nítorí náà, mo wá ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ yóo jẹ́ ti OLUWA.”
Lẹ́yìn náà, wọ́n sin OLUWA#1:28 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní: “Wọ́n sin OLUWA.” Heberu ní, “Ó sin OLUWA.” níbẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KINNI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: