SAMUẸLI KINNI 16
16
Wọ́n Fi Àmì Òróró Yan Dafidi lọ́ba
1OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.”
2Samuẹli dáhùn pé, “Báwo ni n óo ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́, pípa ni yóo pa mí.”
OLUWA dá a lóhùn pé, “Mú ọ̀dọ́ mààlúù kan lọ́wọ́, kí o wí pé o wá rúbọ sí OLUWA ni. 3Pe Jese wá sí ibi ẹbọ náà, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ. N óo dárúkọ ẹnìkan fún ọ, ẹni náà ni kí o fi jọba.”
4Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”
5Samuẹli dáhùn pé, “Alaafia ni. Ẹbọ ni mo wá rú sí OLUWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ bá mi lọ síbi ìrúbọ náà.” Ó ya Jese ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, ó sì pè wọ́n síbi ìrúbọ náà.
6Nígbà tí wọ́n dé, ó wo Eliabu, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú ẹni tí OLUWA yàn nìyí.” 7Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”
8Lẹ́yìn náà, Jese sọ fún Abinadabu pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli wí pé, “OLUWA kò yan eléyìí.” 9Lẹ́yìn náà Jese sọ fún Ṣama pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli tún ní, “OLUWA kò yan eléyìí náà.” 10Jese mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeje kọjá níwájú Samuẹli. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, OLUWA kò yan ọ̀kankan ninu wọn. 11Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?”
Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.”
Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.” 12Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.” 13Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama.
Dafidi ní Ààfin Saulu
14Ẹ̀mí OLUWA kúrò lára Saulu, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA sì ń dà á láàmú. 15Àwọn iranṣẹ Saulu wí fún un pé, “Wò ó! Ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń dà ọ́ láàmú; 16fún àwa iranṣẹ rẹ tí a wà níwájú rẹ láṣẹ láti wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára. Ìgbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bá bà lé ọ, yóo máa fi hapu kọrin, ara rẹ yóo sì balẹ̀.”
17Saulu bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára, kí wọ́n sì mú un wá siwaju òun.
18Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.”
19Saulu bá ranṣẹ sí Jese pé kí ó fi Dafidi, ọmọ rẹ̀ tí ń tọ́jú agbo ẹran ranṣẹ sí òun. 20Jese di ẹrù burẹdi ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ati waini tí wọ́n rọ sinu ìgò aláwọ pẹlu ọmọ ewúrẹ́ kan, ó kó wọn rán Dafidi sí Saulu. 21Dafidi wá sọ́dọ̀ Saulu, ó sì ń bá a ṣiṣẹ́. Saulu fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, ó sì di ẹni tí ń ru ihamọra Saulu. 22Saulu ranṣẹ sí Jese, ó ní, “Jẹ́ kí Dafidi máa bá mi ṣiṣẹ́ nítorí ó ti bá ojurere mi pàdé.” 23Nígbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú bá ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá sórí Saulu, Dafidi a máa ta hapu fún un, ara Saulu á balẹ̀, ẹ̀mí burúkú náà a sì fi í sílẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KINNI 16: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: