SAMUẸLI KINNI 4
4
Wọ́n Gba Àpótí Ẹ̀rí Lọ́wọ́ Àwọn Ọmọ Israẹli
1Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki. 2Àwọn ọmọ ogun Filistini ni wọ́n kọ́ kọlu àwọn ọmọ ogun Israẹli, nígbà tí àwọn mejeeji gbógun pàdé ara wọn, tí wọ́n sì jà fitafita; àwọn ọmọ ogun Filistini ṣẹgun Israẹli, wọ́n sì pa nǹkan bíi ẹgbaaji (4,000) ninu wọn. 3Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” 4Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà.#Eks 25:22
5Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì. 6Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ híhó tí wọn ń hó, wọ́n ní, “Irú ariwo ńlá wo ni àwọn Heberu ń pa ní ibùdó wọn yìí?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àpótí ẹ̀rí OLUWA ni ó dé sí ibùdó àwọn Heberu, 7ẹ̀rù ba àwọn ará Filistia. Wọ́n ní, “Oriṣa kan ti dé sí ibùdó wọn! A gbé! Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí. 8A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀. 9Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.”
10Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn. 11Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli mejeeji.
Ikú Eli
12Ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ti ojú ogun sáré pada lọ sí Ṣilo, ó sì dé ibẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sórí láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. 13Ọkàn Eli dàrú gidigidi nítorí àpótí ẹ̀rí náà, ó sì jókòó lórí àga rẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń wo òréré. Ọkunrin tí ó ti ojú ogun wá bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn fún àwọn ará ìlú, ẹ̀rù ba olukuluku, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké. 14Nígbà tí Eli gbọ́ igbe wọn, ó bèèrè pé, “Kí ni wọ́n ń kígbe báyìí fún?” Ọkunrin náà bá yára wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Eli. 15Eli ti di ẹni ọdún mejidinlọgọrun-un ní àkókò yìí, ojú rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ má ríran mọ́ rárá. 16Ọkunrin náà wí fún un pé, “Ojú ogun ni mo ti sá wá lónìí.”
Eli bá bi í pé, “Kí ló dé, ọmọ mi?”
17Ọkunrin náà dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn ará Filistia. Wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wa, wọ́n pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ rẹ mejeeji pẹlu. Wọ́n sì gbé àpótí Ọlọrun lọ.”
18Nígbà tí ọkunrin náà fẹnu kan àpótí Ọlọ́run, Eli ṣubú sẹ́yìn lórí àpótí tí ó jókòó lé ní ẹnu ọ̀nà, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti di arúgbó, ó sì sanra. Ogoji ọdún ni Eli fi ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.
Ikú Opó Finehasi
19Iyawo Finehasi, ọmọ Eli, wà ninu oyún ní àkókò náà, ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ sì ti súnmọ́ etílé. Nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ, ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú, lẹsẹkẹsẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, tí ó sì bímọ. 20Bí ó ti ń kú lọ, àwọn obinrin tí wọn ń gbẹ̀bí rẹ̀ wí fún un pé, “Ṣe ọkàn gírí, ọkunrin ni ọmọ tí o bí.” Ṣugbọn kò tilẹ̀ kọ ibi ara sí ohun tí wọ́n sọ, kò sì dá wọn lóhùn. 21Ó bá sọ ọmọ náà ní Ikabodu, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀.” Nítorí pé wọ́n ti gba àpótí Ọlọrun ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú. 22Ó ní, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀, nítorí pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KINNI 4: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: