TIMOTI KINNI 1
1
1Èmi Paulu, òjíṣẹ́ Kristi Jesu nípa àṣẹ Ọlọrun Olùgbàlà wa, ati ti Kristi Jesu ìrètí wa, ni mò ń kọ ìwé yìí–
2Sí Timoti ọmọ mi tòótọ́ ninu igbagbọ.#A. Apo 16:1
Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Oluwa wa, kí ó máa wà pẹlu rẹ.
Ìkìlọ̀ nípa Ẹ̀kọ́ Èké
3Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà, 4kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ. 5Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn. 6Àwọn mìíràn ti kùnà nípa irú èyí; wọ́n ti yipada sí ọ̀rọ̀ asán. 7Wọn á fẹ́ máa kọ́ni ní òfin, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ohun tí wọ́n sì ń sọ pẹlu ìdánilójú kò yé wọn.
8A mọ̀ pé òfin jẹ́ ohun tí ó dára bí a bá lò ó bí ó ti tọ́. 9A mọ èyí pé a kò ṣe òfin fún àwọn eniyan rere, bí kò ṣe fún àwọn oníwàkiwà ati àwọn alágídí, àwọn aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn oníbàjẹ́ ati àwọn aláìbìkítà fún ohun mímọ́, àwọn tí wọn máa ń lu baba ati ìyá wọn, 10àwọn àgbèrè, àwọn ọkunrin tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ, àwọn onírọ́, àwọn tí ó ń búra èké, ati àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó dára, 11gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí a fi lé mi lọ́wọ́, ìyìn rere Ọlọrun Ológo, tí ìyìn yẹ fún.
Ọpẹ́ fún Àánú Ọlọrun
12Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jesu Oluwa wa, ẹni tí ń fún mi ní agbára. Mo dúpẹ́ nítorí ó kà mí yẹ láti fún mi ní iṣẹ́ rẹ̀, 13èmi tí ó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí mo kẹ́gàn rẹ̀, mo ṣe inúnibíni sí i, mo tún fi àbùkù kàn án. Ṣugbọn ó ṣàánú mi nítorí n kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é; ninu aigbagbọ ni mo ṣe é.#A. Apo 8:3; 9:4-5 14Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa pàpọ̀jù lórí mi, ati igbagbọ ati ìfẹ́ tí a ní ninu Kristi Jesu. 15Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. 16Ìdí tí ó fi ṣàánú mi nìyí, pé èmi ni Kristi Jesu kọ́kọ́ yọ́nú sí ju ẹnikẹ́ni lọ. Mo wá di àpẹẹrẹ gbogbo àwọn tí wọn yóo gbà á gbọ́ tí wọn yóo sì ní ìyè ainipẹkun. 17Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin.
18Timoti ọmọ mi, ọ̀rọ̀ àṣẹ yìí ni mo fi lé ọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wolii sọ nípa rẹ̀ tí mo fi yàn ọ́, pé kí o ja ìjà rere pẹlu agbára àṣẹ yìí. 19Kí o fi igbagbọ ati ẹ̀rí-ọkàn rere jà. Àwọn nǹkan wọnyi ni àwọn mìíràn kọ̀, tí ọkọ̀ ìgbé-ayé igbagbọ wọn fi rì. 20Irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní Himeneu ati Alẹkisanderu, àwọn tí mo ti fà lé Satani lọ́wọ́ kí ó lè bá wọn wí kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù mọ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
TIMOTI KINNI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: