TIMOTI KINNI 3
3
Irú Ẹni Tí Olùdarí Ìjọ Níláti Jẹ́
1Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí: bí ẹnikẹ́ni bá dàníyàn láti jẹ́ olùdarí, iṣẹ́ rere ni ó fẹ́ ṣe. 2Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni.#Tit 1:6-9 3Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó. 4Ó gbọdọ̀ káwọ́ ilé rẹ̀ dáradára, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. 5Nítorí ẹni tí kò káwọ́ ilé ara rẹ̀, báwo ni ó ṣe lè mójútó ìjọ Ọlọrun? 6Kí ó má jẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onigbagbọ, kí ó má baà gbéraga, kí ó wá bọ́ sọ́wọ́ Satani. 7Ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe onigbagbọ, kí ó má baà bọ̀ sinu ẹ̀gàn, kí tàkúté Satani má baà mú un.
Irú Ẹni Tí Diakoni Níláti Jẹ́
8Bákan náà ni kí àwọn diakoni jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́. Kí wọn má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu meji. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ń mutí para. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ oníwọ̀ra eniyan. 9Wọ́n níláti di ohun ìjìnlẹ̀ igbagbọ mú pẹlu ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́. 10A sì níláti kọ́kọ́ dán wọn wò ná; bí wọ́n bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, kí á wá fi wọ́n sí ipò diakoni. 11Bákan náà ni àwọn obinrin níláti jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́; kí wọn má jẹ́ abanijẹ́. Kí wọn jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, kí wọn jẹ́ ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu ohun gbogbo. 12Diakoni kò gbọdọ̀ ní ju aya kan lọ; ó sì gbọdọ̀ káwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára ati gbogbo ìdílé rẹ̀. 13Nítorí àwọn tí wọn bá ṣe iṣẹ́ diakoni dáradára ti ṣí ọ̀nà ipò gíga fún ara wọn. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìgboyà nípa igbagbọ tí ó wà ninu Kristi Jesu.
Ohun Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀sìn Wa
14Mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, ṣugbọn mò ń kọ ìwé yìí, 15nítorí bí mo bá pẹ́ kí n tó wá, kí o lè mọ̀ bí ó ti yẹ láti darí ètò ilé Ọlọrun, èyí tíí ṣe ìjọ Ọlọrun alààyè, òpó ati ààbò òtítọ́. 16Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ:
Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara,
tí a dá láre ninu ẹ̀mí,
tí àwọn angẹli fi ojú rí,
tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ,
tí a gbàgbọ́ ninu ayé,
tí a gbé lọ sinu ògo.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
TIMOTI KINNI 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: