KRONIKA KEJI 30
30
Ìmúra fún Àjọ Ìrékọjá
1Hesekaya ranṣẹ sí gbogbo Juda ati Israẹli. Ó kọ̀wé sí Efuraimu ati Manase pẹlu, pé kí gbogbo wọ́n wá sí ilé OLUWA ní Jerusalẹmu láti wá ṣe Àjọ Ìrékọjá ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. 2Ọba, àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan ní Jerusalẹmu ti pinnu láti ṣe àjọ náà ní oṣù keji. 3Ṣugbọn wọn kò lè ṣe é ní àkókò rẹ̀ nítorí àwọn alufaa tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ kò tíì pọ̀ tó, àwọn eniyan kò sì tíì péjọ sí Jerusalẹmu tán. 4Ìpinnu yìí dára lójú ọba ati gbogbo ìjọ eniyan. 5Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, pé kí àwọn eniyan wá sí Jerusalẹmu láti pa Àjọ Ìrékọjá mọ́ fún OLUWA Ọlọrun Israẹli; nítorí pé wọn kò tíì ṣe Àjọ Ìrékọjá náà pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 6Àwọn oníṣẹ́ lọ jákèjádò Israẹli ati Juda, pẹlu ìwé láti ọ̀dọ̀ ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Wọ́n kọ sinu ìwé náà pé:#Nọm 9:9-11
“Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israẹli, kí ó lè pada sọ́dọ̀ ẹ̀yin tí ẹ kù tí ẹ sá àsálà, tí ọba Asiria kò pa. 7Ẹ má dàbí àwọn baba yín ati àwọn arakunrin yín tí wọ́n ṣe alaiṣootọ sí OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, tí ó sì sọ ilẹ̀ wọn di ahoro bí ẹ ti rí i yìí. 8Ẹ má ṣe oríkunkun, bí àwọn baba yín. Ẹ fi ara yín fún OLUWA, kí ẹ wá sí ibi mímọ́ rẹ̀, tí ó ti yà sọ́tọ̀ títí lae. Ẹ wá sin OLUWA Ọlọrun yín níbẹ̀, kí ibinu rẹ̀ lè yipada kúrò lọ́dọ̀ yín. 9Bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ OLUWA, àwọn arakunrin yín ati àwọn ọmọ yín yóo rí àánú lọ́dọ̀ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú, wọn yóo sì dá wọn pada sí ilẹ̀ yìí. Nítorí olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní kẹ̀yìn si yín bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ rẹ̀.”
10Àwọn oníṣẹ́ ọba lọ láti ìlú kan dé ekeji jákèjádò ilẹ̀ Efuraimu ati ti Manase, títí dé ilẹ̀ Sebuluni. Ṣugbọn àwọn eniyan fi wọ́n rẹ́rìn-ín, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà. 11Àfi díẹ̀ ninu àwọn ará Aṣeri, Manase, ati Sebuluni ni wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu. 12Ọlọrun lọ́wọ́ sí ohun tí àwọn ará Juda ń ṣe, ó fi sí wọn ní ọkàn láti mú àṣẹ tí ọba ati àwọn olórí pa fún wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.
Àsè Àjọ Ìrékọjá
13Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù keji láti ṣe Àjọ Àìwúkàrà. 14Wọ́n wó gbogbo pẹpẹ oriṣa ati àwọn pẹpẹ turari tí ó wà ní Jerusalẹmu, wọ́n dà wọ́n sí àfonífojì Kidironi. 15Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Ojú ti àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n tètè lọ ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sí ilé OLUWA. 16Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà, gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, eniyan Ọlọrun; àwọn alufaa bẹ̀rẹ̀ sí wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi sí orí pẹpẹ. 17Àwọn tí wọn kò tíì ya ara wọn sí mímọ́ pọ̀ níbi àpéjọ náà, nítorí náà, àwọn ọmọ Lefi bá wọn pa ẹran wọn kí àwọn ẹran náà lè jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. 18Ogunlọ́gọ̀ eniyan, pataki jùlọ ọpọlọpọ ninu àwọn tí wọn wá láti Efuraimu, Manase, Isakari ati Sebuluni, kò tíì ya ara wọn sí mímọ́, sibẹ wọ́n jẹ àsè Àjọ Ìrékọjá, ṣugbọn kì í ṣe ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn Hesekaya gbadura fún wọn pé: “Kí OLUWA rere dáríjì gbogbo àwọn 19tí wọ́n fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni wọ́n fi jẹ àsè àjọ náà gẹ́gẹ́ bí òfin ìwẹ̀nùmọ́ ti ibi mímọ́.” 20OLUWA gbọ́ adura Hesekaya, ó sì wo àwọn eniyan náà sàn. 21Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pa Àjọ Àìwúkàrà mọ́ fún ọjọ́ meje pẹlu ayọ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ń kọrin ìyìn sí OLUWA lojoojumọ pẹlu gbogbo agbára wọn. 22Hesekaya gba àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ṣe dáradára ninu iṣẹ́ OLUWA níyànjú. Àwọn eniyan náà jẹ àsè àjọ náà fún ọjọ́ meje, wọ́n ń rú ẹbọ alaafia, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.
Ayẹyẹ Ẹẹkeji
23Gbogbo wọn tún pinnu láti pa àjọ náà mọ́ fún ọjọ́ meje sí i, wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ ṣe é. 24Hesekaya, ọba fún àwọn eniyan náà ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan láti fi rúbọ. Àwọn ìjòyè náà fún àwọn eniyan ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù, ati ẹgbaarun (10,000) aguntan. Ọpọlọpọ àwọn alufaa ni wọ́n wá, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. 25Gbogbo àwọn ará Juda, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn onílé ati àwọn àlejò tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda, gbogbo wọn ni wọ́n kún fún ayọ̀. 26Gbogbo Jerusalẹmu kún fún ayọ̀ nítorí kò tíì tún sí irú rẹ̀ mọ́ láti ìgbà Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. 27Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n súre fún àwọn eniyan; OLUWA gbọ́ ohùn wọn, adura wọn sì gòkè lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ̀ lọ́run.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KEJI 30: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: