KỌRINTI KEJI 4

4
Ìṣúra ti Ẹ̀mí ninu ìkòkò Amọ̀
1Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì. 2A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere. 3Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí. 4Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun. 5Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi. 6Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.#Jẹn 1:3
7Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa. 8A ní oríṣìíríṣìí ìṣòro, ṣugbọn wọn kò wó wa mọ́lẹ̀; ọkàn wa ń dààmú, ṣugbọn a kò ṣe aláìní ìrètí. 9Àwọn eniyan ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn Ọlọrun kò fi wá sílẹ̀. Wọ́n gbé wa ṣubú, ṣugbọn wọn kò lè pa wá. 10À ń ru ikú Jesu káàkiri lára wa nígbà gbogbo, kí ìyè Jesu lè hàn lára wa. 11Nítorí pé nígbà gbogbo ni à ń fi ẹ̀mí wa wéwu nítorí Jesu, níwọ̀n ìgbà tí a wà láàyè, kí ìyè Jesu lè hàn ninu ẹran-ara wa tí yóo di òkú. 12Ó wá jẹ́ pé ikú ní ń ṣiṣẹ́ ninu wa, nígbà tí ìyè ń ṣiṣẹ́ ninu yín.
13Àkọsílẹ̀ kan sọ pé, “Mo gbàgbọ́, nítorí náà ni mo fi sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó ti jẹ́ pé a ní ẹ̀mí igbagbọ kan náà, àwa náà gbàgbọ́, nítorí náà ni a fi ń sọ̀rọ̀.#O. Daf 116:10 14A mọ̀ pé ẹni tí ó jí Oluwa Jesu dìde yóo jí àwa náà dìde pẹlu Jesu, yóo wá mú àwa ati ẹ̀yin wá sí iwájú rẹ̀. 15Nítorí tiyín ni gbogbo èyí, kí oore-ọ̀fẹ́ lè máa pọ̀ sí i fún ọpọlọpọ eniyan, kí ọpẹ́ yín lè máa pọ̀ sí i fún ògo Ọlọrun.
Ìgbé-Ayé Nípa Igbagbọ
16Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ. 17Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ. 18Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KỌRINTI KEJI 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀