PETERU KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ tí wọ́n wà ní oríṣìíríṣìí ààyè ni a kọ Ìwé Keji láti Ọ̀dọ̀ Peteru sí. Pataki ohun tí ó fa kíkọ rẹ̀ ni ọ̀nà láti tako àwọn olùkọ́ni èké, ati irú ìwà ìṣekúṣe tí irú ẹ̀kọ́ èké wọn lè fà. Kí eniyan di ìmọ̀ tòótọ́ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi mú nìkan ni òògùn ìṣòro yìí. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí gbọdọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ti rí Jesu ní ojúkoojú tí wọ́n sì ti fi etí ara wọn gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nǹkankan tí ó gún ẹni tí ó kọ ìwé yìí lọ́kàn ni ohun tí àwọn kan ń sọ, pé Kristi kò ní pada wá mọ́. Ó ṣe àlàyé pé ìdí tí ó fi dàbí ẹni pé Kristi pẹ́ kí ó tó pada ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, ó fẹ́ kí gbogbo eniyan yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2
Ìpè onigbagbọ 1:3-21
Àwọn olùkọ́ni èké 2:1-22
Ìpadàbọ̀ ìkẹyìn Kristi 3:1-18
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
PETERU KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: