SAMUẸLI KEJI 17
17
Huṣai Ṣi Absalomu lọ́nà
1Lẹ́yìn náà, Ahitofeli wí fún Absalomu pé, “Jẹ́ kí n ṣa ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ọmọ ogun, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Dafidi lọ lálẹ́ òní. 2N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa. 3N óo sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí iyawo tí ó lọ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni o fẹ́ pa, àwọn eniyan yòókù yóo sì wà ní alaafia.” 4Ìmọ̀ràn náà dára lójú Absalomu ati gbogbo àgbààgbà Israẹli.
5Ṣugbọn Absalomu dáhùn pé, “Ẹ pe Huṣai wá, kí á gbọ́ ohun tí òun náà yóo sọ.” 6Nígbà tí Huṣai dé, Absalomu wí fún un pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún wa nìyí, ṣé kí á tẹ̀lé e? Bí kò bá yẹ kí á tẹ̀lé e, sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa.”
7Huṣai dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Kabiyesi ní àkókò yìí, kò dára. 8Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí. 9Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu. 10Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀. 11Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà. 12A óo kọlu Dafidi níbikíbi tí a bá ti bá a, a óo bò wọ́n bí ìgbà tí ìrì bá sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹnikẹ́ni kò sì ní yè ninu òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. 13Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.”
14Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu.
Dafidi Sá fún Ewu Tí Ń Bọ̀
15Huṣai bá lọ sọ fún Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji, irú ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli, ati èyí tí òun fún wọn. 16Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n.
17Jonatani ati Ahimaasi dúró sí ibi orísun Enrogeli, ní ìgbèríko ati máa lọ sí Jerusalẹmu, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fojú kàn wọ́n, pé wọ́n wọ ìlú rárá. Iranṣẹbinrin kan ni ó máa ń lọ sọ ohun tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ fún wọn, àwọn náà á lọ sọ fún Dafidi. 18Ṣugbọn ọmọkunrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Absalomu. Jonatani ati Ahimaasi bá sáré lọ fi ara pamọ́ ní ilé ọkunrin kan ní Bahurimu. Ọkunrin yìí ní kànga kan ní àgbàlá ilé rẹ̀. Àwọn mejeeji bá kó sinu kànga náà. 19Aya ọkunrin náà fi nǹkan dé e lórí, ó sì da ọkà bàbà lé e kí ẹnikẹ́ni má baà fura sí i. 20Nígbà tí àwọn iranṣẹ Absalomu dé ọ̀dọ̀ obinrin náà, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Ahimaasi ati Jonatani wà?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti kọjá sí òdìkejì odò.”
Àwọn ọkunrin náà wá wọn títí, ṣugbọn wọn kò rí wọn. Wọ́n bá pada lọ sí Jerusalẹmu. 21Nígbà tí àwọn ọkunrin náà lọ tán, Ahimaasi ati Jonatani jáde ninu kànga, wọ́n sì lọ ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Dafidi. Wọ́n sọ ohun tí Ahitofeli ti gbèrò láti ṣe sí Dafidi. Wọ́n ní kí ó yára, kí ó rékọjá sí òdìkejì odò náà kíá. 22Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Nígbà tí ilẹ̀ yóo fi mọ́, gbogbo wọn ti kọjá tán.
23Nígbà tí Ahitofeli rí i pé, Absalomu kò tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí òun fún un, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó pada lọ sí ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti ṣètò ilé rẹ̀, ó pokùnso, ó bá kú; wọ́n sì sin ín sí ibojì ìdílé rẹ̀.
24Nígbà tí Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ré odò Jọdani kọjá tán, Dafidi ti dé ìlú tí wọn ń pè ní Mahanaimu. 25Amasa ni Absalomu fi ṣe olórí ogun rẹ̀, dípò Joabu. Itira ará Iṣimaeli ni baba Amasa. Ìyá rẹ̀ sì ni Abigaili, ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruaya, ìyá Joabu. 26Absalomu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí ilẹ̀ Gileadi.
27Nígbà tí Dafidi dé Mahanaimu, Ṣobi, ọmọ Nahaṣi, wá pàdé rẹ̀, láti ìlú Raba, ní ilẹ̀ Amoni. Makiri, ọmọ Amieli, náà wá, láti Lodebari; ati Basilai, láti Rogelimu, ní ilẹ̀ Gileadi. 28Wọ́n kó ibùsùn lọ́wọ́ wá fún wọn, ati àwo, ìkòkò ati ọkà baali, ọkà tí wọ́n ti lọ̀, ati èyí tí wọ́n ti yan, erèé ati ẹ̀fọ́; 29oyin, omi wàrà, ati wàrà sísè. Wọ́n sì kó aguntan wá pẹlu, láti inú agbo wọn fún Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀, kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Nítorí wọ́n rò pé yóo ti rẹ̀ wọ́n, ebi yóo ti máa pa wọ́n, òùngbẹ yóo sì ti máa gbẹ wọ́n, ninu aṣálẹ̀ tí wọ́n wà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 17: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: