SAMUẸLI KEJI 5
5
Dafidi Di Ọba Israẹli ati ti Juda
(1Kron 11:1-9; 14:1-7)
1Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli tọ Dafidi lọ ní Heburoni, wọ́n sọ fún un pé, “Ara kan náà ni wá, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni gbogbo wa. 2Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.” 3Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli wá sí ọ̀dọ̀ ọba ní Heburoni, Dafidi ọba sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n bá fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli. 4Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni, nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba fún ogoji ọdún. 5Ọdún meje ati oṣù mẹfa ni ó fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerusalẹmu ó sì jọba lórí gbogbo Israẹli ati Juda fún ọdún mẹtalelọgbọn.#1 A. Ọba 2:11; 1Kron 3:4; 29:27
6Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà. 7Ṣugbọn Dafidi jagun gba Sioni, ìlú olódi wọn. Sioni sì di ibi tí wọn ń pè ní ìlú Dafidi.#Joṣ 15:63; A. Ada 1:21
8Dafidi bá sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, “Jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pa àwọn ará Jebusi gba ojú àgbàrá lọ pa àwọn afọ́jú ati àwọn arọ tí ọkàn Dafidi kórìíra.” (Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń wí pé, “Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ kò ní lè wọ ilé OLUWA.”)
9Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun ìlú olódi náà, ó ń gbé inú rẹ̀, ó sì yí orúkọ ibẹ̀ pada sí “Ìlú Dafidi”. Ó kọ́ ìlú náà yíká, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, níbi tí wọ́n ti kún ilẹ̀ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn òkè náà. 10Agbára Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i, nítorí pé OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀.
11Hiramu ọba Tire rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi. Ó fi igi Kedari ranṣẹ sí i, pẹlu àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati àwọn tí wọn ń fi òkúta kọ́ ilé, pé kí wọ́n lọ kọ́ ààfin Dafidi. 12Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀.
13Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin. 14Orúkọ àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni; 15Ibihari ati Eliṣua, Nefegi ati Jafia; 16Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti.
Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia
(1Kron 14:8-17)
17Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò. 18Nígbà tí àwọn ará Filistia dé ibi àfonífojì Refaimu, wọ́n dúró níbẹ̀. 19Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?”
OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”
20Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu. 21Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ.
22Àwọn ará Filistia pada, wọ́n tún dúró sí àfonífojì Refaimu. 23Dafidi tún tọ OLUWA lọ láti bèèrè ohun tí yóo ṣe. OLUWA dá a lóhùn pé, “Má ṣe kọlù wọ́n níhìn-ín, ṣugbọn múra, kí o yípo lọ sẹ́yìn wọn, kí o sì kọlù wọ́n ní apá òdìkejì àwọn igi basamu. 24Nígbà tí o bá gbọ́ ìró kan, tí ó bá dàbí ẹni pé, eniyan ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ lórí àwọn igi, ni kí o tó kọlù wọ́n, nítorí pé, OLUWA ti kọjá lọ níwájú rẹ láti ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Filistini.” 25Dafidi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un, ó sì pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Geba títí dé Geseri.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 5: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: