ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 11:17-18

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 11:17-18 YCE

Nítorí náà bí Ọlọrun bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà bí ó ti fún àwa tí a gba Oluwa Jesu Kristi gbọ́, tèmi ti jẹ́, tí n óo wá dí Ọlọrun lọ́nà?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò tún ní ìkọminú mọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun. Wọ́n ní, “Èyí ni pé Ọlọrun ti fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù náà ní anfaani láti ronupiwada kí wọ́n lè ní ìyè.”