ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 24
24
Ẹ̀sùn Tí Wọ́n fi Kan Paulu
1Lẹ́yìn ọjọ́ marun-un, Anania olórí Alufaa dé pẹlu àwọn àgbààgbà ati agbẹjọ́rò kan tí ń jẹ́ Tatulu. Wọ́n ro ẹjọ́ Paulu fún gomina. 2Nígbà tí wọ́n pe Paulu, Tatulu bẹ̀rẹ̀ sí rojọ́. Ó ní:
“Fẹliksi ọlọ́lá jùlọ, à ń jọlá alaafia tí ẹ mú wá lọpọlọpọ, a sì ń gbádùn oríṣìíríṣìí àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe lọ́tùn-ún lósì fún àwọn ọmọ ilẹ̀ wa. 3Ọjọ́ iwájú ni ẹ̀ ń rò tí ẹ fi ń ṣe èyí nígbà gbogbo. A dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ yín. 4N kò fẹ́ gbà yín ní àkókò títí, mo bẹ̀ yín kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbọ́ ohun tí a níláti sọ ní ṣókí. 5Onijamba eniyan ni ọkunrin yìí; rúkèrúdò ni ó ń dá sílẹ̀ láàrin àwọn Juu ní gbogbo àgbáyé. Ọ̀gá ni ninu ẹgbẹ́ àwọn Nasarene. 6A ká a mọ́ ibi tí ó ti fẹ́ mú ohun ẹ̀gbin wọ inú Tẹmpili, a bá mú un. [A fẹ́ jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí òfin wa. 7Ṣugbọn ọ̀gágun Lisia wá fi ipá gbà á kúrò lọ́wọ́ wa, ni ó bá mú un lọ. 8Òun ni ó pàṣẹ pé kí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wá siwaju yín.] Bí ẹ bá wádìí lẹ́nu òun fúnrarẹ̀, ẹ óo rí i pé òtítọ́ ni gbogbo ẹjọ́ rẹ̀ tí a fi sùn yín.” 9Àwọn Juu náà gbè é lẹ́sẹ̀; wọ́n ní bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ rí.
Paulu Sọ tẹnu Rẹ̀ níwájú Fẹliksi
10Gomina wá mi orí sí Paulu. Paulu wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Ó ní:
“Ó dùn mọ́ mi pé níwájú yín ni n óo ti sọ ti ẹnu mi. Nítorí mo mọ̀ pé ẹ ti ń ṣe onídàájọ́ ní orílẹ̀-èdè wa yìí fún ọpọlọpọ ọdún. 11Kò ju ọjọ́ mejila lọ nisinsinyii tí mo lọ ṣọdún ní Jerusalẹmu. Ẹ lè wádìí èyí. 12Ẹnìkan kò rí mi kí n máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn ninu Tẹmpili. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò rí mi pé mo kó àwọn eniyan jọ láti dá rúkèrúdò sílẹ̀, ìbáà ṣe ninu ilé ìpàdé ni tabi níbikíbi láàrin ìlú. 13Wọn kò lè rí ohunkohun wí tí ẹ lè rí dìmú ninu ẹjọ́ tí wọn wá ń rò mọ́ mi lẹ́sẹ̀ nisinsinyii. 14Ṣugbọn mo jẹ́wọ́ ohun kan fun yín: lóòótọ́ ni mò ń sin Ọlọrun àwọn baba wa ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Mo gba gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé Òfin ati ninu ìwé àwọn wolii. 15Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú. 16Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.
17“Ó ti tó ọdún mélòó kan tí mo ti dé Jerusalẹmu gbẹ̀yìn. Ìtọrẹ àánú ni mo mú wá fún àwọn orílẹ̀-èdè mi, kí n sì rúbọ.#A. Apo 21:17-28 18Níbi tí mo gbé ń ṣe èyí, wọ́n rí mi ninu Tẹmpili. Mo ti wẹ ara mi mọ́ nígbà náà. N kò kó èrò lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fa ìjàngbọ̀n. 19Ṣugbọn àwọn Juu kan láti Esia wà níbẹ̀. Àwọn ni ó yẹ kí wọ́n wá siwaju yín bí wọn bá ní ẹ̀sùn kan sí mi. 20Tabi, kí àwọn tí wọ́n wà níhìn-ín fúnra wọn sọ nǹkan burúkú kan tí wọ́n rí pé mo ṣe nígbà tí mo wà níwájú ìgbìmọ̀. 21Àfi gbolohun kan tí mo sọ nígbà tí mo dúró láàrin wọn, pé, ‘Ìdí tí a fi mú mi wá fún ìdájọ́ níwájú yín lónìí ni pé mo ní igbagbọ pé àwọn òkú yóo jinde.’ ”#A. Apo 23:6
22Fẹliksi bá sún ọjọ́ ìdájọ́ siwaju. Ó mọ ohun tí ọ̀nà igbagbọ jẹ́ dáradára. Ó ní, “Nígbà tí ọ̀gágun Lisia bá dé, n óo sọ bí ọ̀rọ̀ yín ti rí lójú mi.” 23Ó bá pàṣẹ fún balogun ọ̀rún pé kí ó máa ṣọ́ Paulu. Ó ní kí ó máa há a mọ́lé, ṣugbọn kí ó ní òmìnira díẹ̀, kí ó má sì dí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Wọ́n Ti Paulu mọ́lé
24Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀. 25Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ tirẹ̀ nípa ìwà rere, ìkóra-ẹni-níjàánu, ati ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹliksi. Ó bá sọ fún Paulu pé, “Ó tó gẹ́ẹ́ lónìí. Máa lọ. Nígbà tí mo bá ráyè n óo tún ranṣẹ pè ọ́.” 26Sibẹ ó ń retí pé Paulu yóo fún òun ní owó. Nítorí náà, a máa ranṣẹ pè é lemọ́lemọ́ láti bá a sọ̀rọ̀.
27Lẹ́yìn ọdún meji Pọkiu Fẹstu gba ipò Fẹliksi. Nítorí Fẹliksi ń wá ojurere àwọn Juu, ó fi Paulu sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 24: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: