DANIẸLI 5

5
Àsè Beṣasari
1Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn. 2Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí. 3Wọ́n bá kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí wọ́n kó ninu tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí. 4Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta.
5Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé. 6Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn. 7Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.” 8Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 9Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.
10Nígbà tí ayaba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ó wọ inú gbọ̀ngàn àsè náà, ó sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, kí ọba kí ó pẹ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dààmú rẹ tabi kí ó mú kí ojú rẹ fàro. 11Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀; 12nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.”
Daniẹli Túmọ̀ Àkọsílẹ̀ náà
13Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda? 14Mo ti gbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ń bẹ ninu rẹ; ati pé o ní ìmọ̀, òye, ati ọgbọ́n tí kò lẹ́gbẹ́. 15Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ati aláfọ̀ṣẹ wá siwaju mi, wọ́n gbìyànjú láti ka àkọsílẹ̀ yìí, kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè ṣe é. 16Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè túmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀, o sì lè yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú; nisinsinyii, bí o bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, wọn óo wọ̀ ọ́ ní aṣọ elése àlùkò, wọn óo sì fi ẹ̀gbà wúrà sí ọ lọ́rùn, o óo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ní ìjọba mi.”
17Daniẹli dá ọba lóhùn, ó ní, “Jẹ́ kí ẹ̀bùn rẹ máa gbé ọwọ́ rẹ, kí o sì fi ọrẹ rẹ fún ẹlòmíràn. Ṣugbọn n óo ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, n óo sì túmọ̀ rẹ̀.
18“Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá. 19Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀. 20Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò. 21A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú.
22“Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. 23Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. 24Ìdí nìyí tí ó fi rán ọwọ́ kan jáde láti kọ àkọsílẹ̀ yìí.
25“Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’ 26Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. 27TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n. 28PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.”
29Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba. 30Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea. 31Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DANIẸLI 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀