DANIẸLI 9
9
Daniẹli Gbadura fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
1Ní ọdún kinni tí Dariusi, ọmọ Ahasu-erusi, ará Mede, jọba ní Babiloni, 2èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún.#Jer 25:11; 29:10 3Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ OLUWA Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ mò ń gbadura tọkàntọkàn pẹlu ààwẹ̀; mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo sì jókòó sinu eérú. 4Mo gbadura sí OLUWA Ọlọrun mi, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi.
Mo ní, “OLUWA Ọlọrun, tí ó tóbi, tí ó bani lẹ́rù, tíí máa ń pa majẹmu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.
5“A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀. 6A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. 7Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ.#Bar 1:15-17 8OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́. 9Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. 10A kò gbọ́ tìrẹ OLUWA Ọlọrun wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò pa òfin rẹ tí o fi rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ sí wa mọ́. 11Gbogbo Israẹli ti rú òfin rẹ, wọ́n ti pada lẹ́yìn rẹ, wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́ tìrẹ. Nítorí náà, ègún ati ìbúra tí Mose, iranṣẹ rẹ kọ sinu ìwé òfin ti ṣẹ mọ́ wa lára.#Bar 1:19-23 12Ohun tí o sọ pé o óo ṣe sí àwa ati àwọn ọba wa náà ni o ṣe sí wa, tí àjálù ńlá fi dé bá wa. Irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí kò ṣẹlẹ̀ sí ìlú kan rí, ninu gbogbo àwọn ìlú ayé yìí. 13Gbogbo ìyọnu tí a kọ sinu òfin Mose ti dé bá wa, sibẹ a kò wá ojurere OLUWA Ọlọrun wa, kí á yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí á sì tẹ̀lé ọ̀nà òtítọ́ rẹ̀. 14Nítorí náà, OLUWA ti mú kí ìyọnu dé bá wa, ó sì rọ̀jò rẹ̀ lé wa lórí; olódodo ni OLUWA Ọlọrun wa ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, sibẹ a kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.
15“Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, ìwọ tí o kó àwọn eniyan rẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu agbára ńlá, nítorí orúkọ rẹ tí à ń ranti títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe nǹkan burúkú.#Bar 2:11-13 16OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òdodo rẹ, dáwọ́ ibinu ati ìrúnú rẹ dúró lórí Jerusalẹmu, ìlú rẹ, òkè mímọ́ rẹ; nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára àwọn baba wa, ti sọ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan rẹ, di àmúpòwe láàrin àwọn tí ó yí wa ká. 17Nítorí náà Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, ṣí ojurere wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti di ahoro.#Bar 2:14 18Gbọ́ tiwa, Ọlọrun mi, ṣíjú wò wá, bí àwa ati ìlú tí à ń pe orúkọ rẹ mọ́, ti wà ninu ìsọdahoro. Kì í ṣe nítorí òdodo wa ni a ṣe ń gbadura sí ọ, ṣugbọn nítorí pé aláàánú ni ọ́.#Bar 2:19 19Gbọ́ tiwa, OLUWA, dáríjì wá, tẹ́tí sí wa, OLUWA, wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, má sì jẹ́ kí ó pẹ́, nítorí orúkọ rẹ, tí a fi ń pe ìlú rẹ ati àwọn eniyan rẹ.”
Geburẹli Túmọ̀ Àlá náà
20Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ èmi ati ti àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, mo kó ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLUWA Ọlọrun mi lọ, nítorí òkè mímọ́ rẹ̀. 21Bí mo ti ń gbadura, ni Geburẹli, tí mo rí lójúran ní àkọ́kọ́ bá yára fò wá sọ́dọ̀ mi, ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́.#Luk 1:19,26 22Ó wá ṣe àlàyé fún mi, ó ní, “Daniẹli, àlàyé ìran tí o rí ni mo wá ṣe fún ọ. 23Bí o ti bẹ̀rẹ̀ sí gbadura ni àṣẹ dé, òun ni mo sì wá sọ fún ọ́; nítorí àyànfẹ́ ni ọ́. Nisinsinyii, farabalẹ̀ ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ náà, kí òye ìran náà sì yé ọ.
24“Ọlọrun ti fi àṣẹ sí i pé, lẹ́yìn aadọrin ọdún lọ́nà meje ni òun óo tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati ti ìlú mímọ́ rẹ jì wọ́n, tí òun óo ṣe ètùtù fún ìwà burúkú wọn, tí òun óo mú òdodo ainipẹkun ṣẹ, tí òun óo fi èdìdì di ìran ati àsọtẹ́lẹ̀ náà, tí òun óo sì fi òróró ya Ilé Mímọ́ Jùlọ rẹ̀ sọ́tọ̀. 25Mọ èyí, kí ó sì yé ọ, pé láti ìgbà tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti tún Jerusalẹmu kọ́, di ìgbà tí ẹni àmì òróró Ọlọrun, tíí ṣe ọmọ Aládé, yóo dé, yóo jẹ́ ọdún meje lọ́nà meje. Lẹ́yìn náà, ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje ni a óo sì fi tún un kọ́, yóo ní òpópónà, omi yóo sì yí i po; ṣugbọn yóo jẹ́ àkókò ìyọnu. 26Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé. 27Ìjòyè yìí yóo bá ọpọlọpọ dá majẹmu ọdún meje tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Fún ìdajì ọdún meje náà, yóo fi òpin sí ẹbọ rírú ati ọrẹ. Olùsọdahoro yóo gbé ohun ìríra ka téńté orí pẹpẹ ní Jerusalẹmu. Ohun ìríra náà yóo sì wà níbẹ̀ títí tí ìgbẹ̀yìn tí Ọlọrun ti fàṣẹ sí yóo fi dé bá olùsọdahoro náà.”#Dan 11:31; 12:11; 1 Makab 1:44-50,54; Mat 24:15; Mak 13:14
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
DANIẸLI 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: