EFESU 4
4
Ìṣọ̀kan Ara Kristi
1Nítorí náà, èmi tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Oluwa, ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, bí irú ìpè tí Ọlọrun pè yín. 2Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà.#Kol 3:12-13 3Ẹ ní ìtara láti pa ìṣọ̀kan ti Ẹ̀mí mọ́ ninu alaafia tí ó so yín pọ̀. 4Ara kan ni ó wà, ati Ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́ bí ìpè tí a ti pè yín ti jẹ́ ti ìrètí kan. 5Oluwa kan ṣoṣo ni ó wà, ati igbagbọ kan, ati ìrìbọmi kan. 6Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba gbogbo eniyan, òun ni olórí ohun gbogbo, tí ó ń ṣiṣẹ́ ninu ohun gbogbo, tí ó sì wà ninu ohun gbogbo.
7Ṣugbọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹ̀bùn tí Kristi fi fún wa. 8Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé,#O. Daf 68:18
“Nígbà tí ó lọ sí òkè ọ̀run,
ó kó àwọn ìgbèkùn lẹ́yìn,
ó sì fi ẹ̀bùn fún àwọn eniyan.”
9Nígbà tí ó sọ pé, “Ó lọ sí òkè ọ̀run,” ìtumọ̀ èyí kò lè yéni tóbẹ́ẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ wá sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 10Òun kan náà tí ó wá sí ìsàlẹ̀ ni ó lọ sí òkè, tí ó tayọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́run, kí ó lè sọ gbogbo nǹkan di kíkún. 11Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti jẹ́ aposteli, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ wolii, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ ajíyìnrere, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ alufaa ati olùkọ́ni. 12Àwọn ẹ̀bùn wọnyi wà fún lílò láti mú kí ara àwọn eniyan Ọlọrun lè dá ṣáṣá kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, ati láti mú kí ara Kristi lè dàgbà. 13Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà. 14A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri. 15Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí. 16Òun ni ó mú kí gbogbo ẹ̀yà ara wà ní ìṣọ̀kan, tí gbogbo oríkèé-ríkèé ara wa sì wà ní ipò wọn, pẹlu iṣan tí ó mú wọn dúró, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipò olukuluku wọn, tí gbogbo ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan fi ń dàgbà, tí ó ń mú kí gbogbo ara rẹ̀ dàgbà ninu ìfẹ́.#Kol 2:19
Ìgbé-Ayé ti Àtijọ́ ati ti Ìsinsìnyìí
17Nítorí náà, mò ń sọ fun yín, mo sì ń bẹ̀ yín ní orúkọ Oluwa pé, kí ẹ má máa hùwà bíi ti àwọn abọ̀rìṣà mọ́, àwọn tí wọn ń hùwà gẹ́gẹ́ bí èrò asán ọkàn wọn. 18Ọkàn àwọn yìí ti ṣókùnkùn, ó sì ti yàtọ̀ pupọ sí irú ìgbé-ayé tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí òpè ni wọ́n, ọkàn wọn ti le. 19Wọn kò bìkítà: wọ́n ti fi ara wọn fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara nípa oríṣìíríṣìí ìwà burúkú nítorí ojúkòkòrò.
20Ṣugbọn a kò kọ́ ẹ̀yin bẹ́ẹ̀ nípa Kristi. 21Ẹ ti gbọ́ nípa Jesu, a sì ti fi òtítọ́ rẹ̀ kọ yín, 22pé kí ẹ jìnnà sí irú ìwà àtijọ́ tí ẹ ti ń hù, ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tíí máa tan eniyan lọ sinu ìparun.#Kol 3:9 23Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ yín di ẹni titun ninu ọkàn yín. 24Kí ẹ wá gbé ẹni titun nnì tí Ọlọrun dá wọ̀, kí ẹ lè máa ṣe òdodo, kí ẹ sì máa hu ìwà mímọ́ ninu òtítọ́.#a Kol 3:10; b Jẹn 1:26; Ọgb 9:3
Ìlànà fún Ìgbé-Ayé Titun
25Nítorí náà, ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa bá ẹnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí gbogbo wa jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà.#Sak 8:16 26Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu.#O. Daf 4:4 27Ẹ má fi ààyè gba Èṣù. 28Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní. 29Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani. 30Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà. 31Ẹ níláti mú gbogbo inú burúkú, ìrúnú, ibinu, ariwo ati ìsọkúsọ kúrò láàrin yín ati gbogbo nǹkan burúkú. 32Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.#Kol 3:13
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
EFESU 4: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: