ẸSITA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Ẹsita jẹ́ ìtàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilé tí ọba Pasia máa ń gbé ní ìgbà òtútù. Ìtàn inú ìwé náà dá lórí Ẹsita, akọni obinrin, ayaba, ọmọ ilẹ̀ Juu. Ó gba àwọn eniyan rẹ̀ là lọ́wọ́ ìparun àwọn ọ̀tá wọn, nítorí ẹ̀mí ìgboyà ati ìfẹ́ àwọn eniyan rẹ̀ tí ó ní, láìbìkítà bí òun kú, bí òun yè. Ìwé yìí ṣe àlàyé ìtumọ̀ ọdún Purimu tí àwọn Juu máa ń ṣe, ati bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ẹsita di ayaba 1:1–2:23
Àwọn ọ̀tẹ̀ tí Hamani dì 3:1–5:14
Ikú Hamani 6:1–7:10
Àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn 8:1–10:3

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸSITA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀