ẸKISODU 31
31
Àwọn Òṣìṣẹ́ fún Àgọ́ OLUWA
(Eks 35:30–36:1)
1OLUWA sọ fún Mose pé, 2“Wò ó, mo ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. 3Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà, 4láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, 5láti dá oríṣìíríṣìí àrà sí ara òkúta ati láti tò ó, láti gbẹ́ igi ati láti fi oríṣìíríṣìí ohun èlò ṣe iṣẹ́ ọnà. 6Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ. 7Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àgọ́ àjọ, ati àpótí ẹ̀rí ati ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò àgọ́, 8ati tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, pẹpẹ turari, 9pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; 10ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, 11ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.”
Ọjọ́ Ìsinmi
12OLUWA rán Mose, ó ní, 13“Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, nítorí pé òun ni àmì tí ó wà láàrin èmi pẹlu yín ní ìrandíran yín; kí ẹ lè mọ̀ pé, èmi OLUWA yà yín sọ́tọ̀ fún ara mi. 14Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀. 15Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, èyí tí ó jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ ìsinmi, pípa ni kí wọ́n pa á.#Eks 20:8-11; 23:12; 34:21; 35:2; Lef 23:3; Diut 5:12-14. 16Nítorí náà, àwọn eniyan Israẹli yóo máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, wọn yóo máa ranti rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì majẹmu ní ìrandíran wọn. 17Ọjọ́ náà jẹ́ àmì ayérayé tí ó wà láàrin èmi ati àwọn eniyan Israẹli, pé ọjọ́ mẹfa ni èmi Ọlọrun fi dá ọ̀run ati ayé, ati pé ní ọjọ́ keje, mo dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró, mo sì sinmi.’ ”#Eks 20:11.
18Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ẸKISODU 31: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: