ẸSIRA 6
6
Wọ́n Rí Àkọsílẹ̀ Àṣẹ tí Kirusi Ọba Pa
1Dariusi ọba pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí fínnífínní ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí ó wà ní ààfin, ní ilẹ̀ Babiloni. 2Ṣugbọn ní ìlú Ekibatana, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Media, ni wọ́n ti rí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí pé:
3“Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi ni ó pàṣẹ pé kí wọn tún ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́ fún ìrúbọ ati fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gíga ilé Ọlọrun náà gbọdọ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27), kí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27). 4Kí ògiri jẹ́ ìlè igi kan lórí ìlè òkúta mẹta. Ninu ilé ìṣúra ààfin ọba ni kí wọ́n ti mú owó kí wọ́n fi san owó iṣẹ́ náà. 5Gbogbo ohun èlò ìṣúra wúrà ati fadaka inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, tí Nebukadinesari kó lọ sí Babiloni, ni kí wọ́n kó pada wá sí Jerusalẹmu, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ààyè wọn ninu ilé Ọlọrun.”
Dariusi Pàṣẹ pé Kí Wọ́n Máa Bá Iṣẹ́ Lọ
6Nígbà náà ni Dariusi ọba désì ìwé Tatenai pada, ó ní,
“Sí Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò, ati Ṣetari Bosenai ati àwọn gomina ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. 7Ẹ fi wọ́n sílẹ̀, ẹ má dí wọn lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí gomina Juda ati àwọn àgbààgbà Juu tún ilé Ọlọrun náà kọ́ síbi tí ó wà tẹ́lẹ̀. 8Ati pé, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe láti ran àwọn àgbààgbà Juu lọ́wọ́ láti kọ́ ilé Ọlọrun náà pé: Ninu àpò ìṣúra ọba ati lára owó bodè ni kí ẹ ti mú, kí ẹ fi san gbogbo owó àwọn òṣìṣẹ́ ní àsanpé, kí iṣẹ́ lè máa lọ láìsí ìdádúró. 9Lojoojumọ, ni kí ẹ máa fún àwọn alufaa tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ní iye akọ mààlúù, àgbò, aguntan pẹlu ìwọ̀n ọkà, iyọ̀, ọtí waini ati òróró olifi, tí wọn bá bèèrè fún ẹbọ sísun sí Ọlọrun ọ̀run. 10Kí wọ́n baà lè rú ẹbọ tí yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọrun ọ̀run, kí wọ́n sì lè máa gbadura ibukun fún èmi ati àwọn ọmọ mi. 11Siwaju sí i, mo tún pàṣẹ pé, bí ẹnikẹ́ni bá rú òfin mi yìí, kí wọ́n yọ ọ̀kan ninu igi òrùlé rẹ̀; kí wọ́n gbẹ́ ẹ ṣóńṣó, kí wọ́n tì í bọ̀ ọ́ láti ìdí títí dé orí rẹ̀. Kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ààtàn. 12Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.”
Wọ́n Ya Tẹmpili sí Mímọ́
13Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. 14Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia. 15Wọ́n parí kíkọ́ Tẹmpili náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Adari, ní ọdún kẹfa ìjọba Dariusi. 16Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà. 17Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila. 18Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose.#(a) Hag 1:1 (b) Sek 1:1
Àjọ Ìrékọjá
19Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá. 20Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn. 21Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà. 22Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́.#Eks 12:1-20
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ẸSIRA 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: