GALATIA 6

6
Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́
1Ará, bí ẹ bá ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ẹnìkan lọ́wọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ̀mí ń darí ìgbé-ayé yín mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò pẹlu ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ṣọ́ra rẹ, kí á má baà dán ìwọ náà wò. 2Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ. 3Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ. 4Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn. 5Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀.
6Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀.
7Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká. 8Nítorí àwọn tí ó bá ń gbin nǹkan ti Ẹ̀mí yóo ká àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí, tíí ṣe ìyè ainipẹkun. 9Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá. 10Nítorí náà, bí a bá ti ń rí ààyè kí á máa ṣe oore fún gbogbo eniyan, pàápàá fún àwọn ìdílé onigbagbọ.
Gbolohun Ìparí
11Ọwọ́ ara mi ni mo fi kọ ìwé yìí si yín, ẹ wò ó bí ó ti rí gàdàgbà-gadagba! 12Gbogbo àwọn tí wọn ń fẹ́ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn mọ̀ wọ́n ní ẹni rere ni wọ́n fẹ́ fi ipá mu yín kọlà, kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn má baà ṣe inúnibíni sí wọn nítorí agbelebu Kristi. 13Nítorí àwọn tí wọ́n kọlà pàápàá kì í pa gbogbo òfin mọ́. Ṣugbọn wọ́n fẹ́ kí ẹ kọlà kí wọ́n máa fi yín fọ́nnu pé àwọn mu yín kọlà. 14Ṣugbọn ní tèmi, kí á má rí i pé mò ń fọ́nnu kiri àfi nítorí agbelebu Oluwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ayé yìí ti di ohun tí a kàn mọ́ agbelebu lójú mi, tí èmi náà sì di ẹni tí a kàn mọ́ agbelebu lójú rẹ̀. 15Nítorí ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó já mọ́ nǹkankan. Ohun tí ó ṣe pataki ni ẹ̀dá titun. 16Kí alaafia ati àánú Ọlọrun kí ó wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá ń gbé ìgbé-ayé wọn nípa ìlànà yìí, ati pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun.
17Láti ìgbà yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́, nítorí ojú pàṣán wà ní ara mi tí ó fihàn pé ti Jesu ni mí.
18Ará, kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa wa kí ó wà pẹlu yín. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

GALATIA 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀