Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè.
OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀. Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire.
Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin. Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà. Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu. Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate.
OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.”
Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́.
Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ.