JẸNẸSISI 21
21
A Bí Isaaki
1OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. 2Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un.#Heb 11:11 3Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki. 4Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un.#Jẹn 17:12; A. Apo 7:8 5Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un. 6Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.” 7Ó tún wí pé, “Ta ni ó lè sọ fún Abrahamu pé Sara yóo fún ọmọ lọ́mú? Sibẹsibẹ mo bí ọmọ fún un nígbà tí ó ti di arúgbó.”
8Ọmọ náà dàgbà, ó sì já lẹ́nu ọmú, Abrahamu sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí ọmọ náà já lẹ́nu ọmú.
Wọ́n Lé Hagari ati Iṣimaeli Jáde nílé
9Ní ọjọ́ kan, Sara rí ọmọ tí Hagari, ará Ijipti bí fún Abrahamu, níbi tí ó ti ń bá Isaaki, ọmọ rẹ̀, ṣeré. 10Sara bá pe Abrahamu, ó sọ fún un pé, “Lé ẹrubinrin yìí jáde pẹlu ọmọ rẹ̀, nítorí pé ọmọ ẹrubinrin yìí kò ní jẹ́ àrólé pẹlu Isaaki ọmọ mi.”#Gal 4:29-30 11Ọ̀rọ̀ yìí kò dùn mọ́ Abrahamu ninu nítorí Iṣimaeli, ọmọ rẹ̀. 12Ṣugbọn Ọlọrun wí fún Abrahamu pé, “Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ati ti ẹrubinrin rẹ, ohunkohun tí Sara bá wí fún ọ ni kí o ṣe, nítorí pé orúkọ Isaaki ni wọn yóo fi máa pe atọmọdọmọ rẹ.#Rom 9:7; Heb 11:18 13N óo sọ ọmọ ẹrubinrin náà di orílẹ̀ èdè ńlá pẹlu, nítorí ọmọ rẹ ni òun náà.”
14Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó mú oúnjẹ ati omi sinu ìgò aláwọ kan, ó dì wọ́n fún Hagari, ó kó wọn kọ́ ọ léjìká, ó fa ọmọ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó ní kí wọn ó jáde kúrò nílé. Hagari jáde nílé, ó bá ń rìn káàkiri ninu aginjù Beeriṣeba. 15Nígbà tí omi tán ninu ìgò aláwọ náà, Hagari fi ọmọ náà sílẹ̀ lábẹ́ igbó ṣúúrú kan tí ó wà níbẹ̀. 16Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.”
17Bí ó ṣe jókòó tí ó takété sí ọmọ náà, ọmọ fi igbe ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ọlọrun gbọ́ igbe ọmọ náà, angẹli Ọlọrun bá ké sí Hagari láti ọ̀run wá, ó bi í pé, “Kí ni ó ń dààmú ọkàn rẹ, Hagari? Má bẹ̀rù, nítorí Ọlọrun ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí ó wà. 18Dìde, lọ gbé e, kí o sì rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, nítorí n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.” 19Ọlọrun bá la Hagari lójú, ó rí kànga kan, ó rọ omi kún inú ìgò aláwọ rẹ̀, ó sì fún ọmọdekunrin náà mu. 20Ọlọrun wà pẹlu ọmọ náà, ó dàgbà, ó ń gbé ninu aginjù, ó sì mọ ọfà ta tóbẹ́ẹ̀ tí ó di atamátàsé. 21Ó ń gbé inú aginjù Parani, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ aya fún un ní ilẹ̀ Ijipti.
Majẹmu láàrin Abrahamu ati Abimeleki
22Ní àkókò náà, Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sọ fún Abrahamu pé, “Ọlọrun wà pẹlu rẹ ninu ohun gbogbo tí ò ń ṣe.#Jẹn 26:26. 23Nítorí náà, fi Ọlọrun búra fún mi níhìn-ín yìí, pé o kò ní hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi, tabi sí àwọn ọmọ mi, tabi sí ìran mi, ṣugbọn bí mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà yóo jẹ́ olóòótọ́ sí mi ati sí ilẹ̀ tí o ti ń ṣe àtìpó.”
24Abrahamu bá sọ pé òun yóo búra.
25Abrahamu rò fún Abimeleki bí àwọn iranṣẹ Abimeleki ti fi ipá gba kànga omi kan lọ́wọ́ rẹ̀, 26Abimeleki bá dá a lóhùn, ó ní “N kò mọ ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, o kò sọ fún mi, n kò gbọ́ nǹkankan nípa rẹ̀, àfi bí o ti ń sọ yìí.” 27Abrahamu fún Abimeleki ní aguntan ati mààlúù, àwọn mejeeji bá jọ dá majẹmu. 28Abrahamu ya abo ọmọ aguntan meje ninu agbo rẹ̀ sọ́tọ̀. 29Abimeleki bá bi Abrahamu, ó ní, “Kí ni ìtumọ̀ abo ọmọ aguntan meje tí o yà sọ́tọ̀ wọnyi?”
30Abrahamu dá a lóhùn pé, “Gba abo ọmọ aguntan meje wọnyi lọ́wọ́ mi, kí o lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”
31Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Beeriṣeba, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn mejeeji ti búra.
32Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe dá majẹmu ní Beeriṣeba. Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sì pada lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. 33Abrahamu gbin igi tamarisiki kan sí Beeriṣeba, ó sì ń sin OLUWA Ọlọrun ayérayé níbẹ̀. 34Abrahamu gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ìgbà pípẹ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JẸNẸSISI 21: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: