JẸNẸSISI 25

25
Àwọn Ọmọ Mìíràn Tí Abrahamu Bí
(1Kron 1:32-33)
1Abrahamu fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura. 2Ketura bí Simirani, Jokiṣani, Medani, Midiani, Iṣibaku ati Ṣua fún un. 3Jokiṣani ni baba Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ Dedani ni Aṣurimu, Letuṣimu ati Leumimu. 4Àwọn ọmọ Midiani ni Efai, Eferi, Hanoku, Abida ati Elidaa. Àwọn ni àwọn ìran tó ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ketura.
5Ṣugbọn Isaaki ni Abrahamu kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ fún. 6Ẹ̀bùn ni ó fún gbogbo ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn bí fún un, kí ó tó kú ni ó sì ti ní kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ Isaaki, kí wọ́n lọ máa gbé ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.
Ikú ati Ìsìnkú Abrahamu
7Ọdún tí Abrahamu gbé láyé jẹ́ aadọsan-an ọdún ó lé marun-un (175), 8ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́, kí ó tó kú. 9Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣimaeli, sin òkú rẹ̀ sinu ihò òkúta Makipela, ninu pápá Efuroni, ọmọ Sohari, ará Hiti, níwájú Mamure. 10Ilẹ̀ tí Abrahamu rà lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n sin ín sí pẹlu Sara aya rẹ̀,#Jẹn 23:3-16 11Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọrun bukun Isaaki ọmọ rẹ̀. Isaaki sì ń gbé Beeri-lahai-roi.
Àwọn Ìran Iṣimaeli
(1Kron 1:28-31)
12Ìran Iṣimaeli, ọmọ Abrahamu, tí Hagari, ará Ijipti, ọmọ-ọ̀dọ̀ Sara bí fún un nìyí: 13Àwọn ọmọkunrin Iṣimaeli nìwọ̀nyí bí a ti bí wọn tẹ̀lé ara wọn: Nebaiotu, Kedari, Adibeeli, 14Mibisamu, Miṣima, Duma, Masa, 15Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi ati Kedema. 16Àwọn ni ọmọkunrin Iṣimaeli. Wọ́n jẹ́ ọba ẹ̀yà mejila, orúkọ wọn ni wọ́n sì fi ń pe àwọn ìletò ati àgọ́ wọn. 17Iye ọdún tí Iṣimaeli gbé láyé jẹ́ ọdún mẹtadinlogoje (137). Nígbà tí ó kú a sin ín pẹlu àwọn eniyan rẹ̀. 18Àwọn ọmọ Iṣimaeli sì ń gbé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Hafila títí dé Ṣuri, tí ó wà ní òdìkejì Ijipti, ní apá Asiria. Wọ́n tẹ̀dó sí òdìkejì àwọn eniyan wọn.
Ìbí Esau ati Jakọbu
19Ìran Isaaki ọmọ Abrahamu nìyí, Abrahamu ni baba Isaaki. 20Nígbà tí Isaaki di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Rebeka. Rebeka jẹ́ ọmọ Betueli, ará Aramea, tí ń gbé Padani-aramu, ó sì tún jẹ́ arabinrin Labani, ara Aramea. 21Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún. 22Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA.
23OLUWA wí fún un pé,#Rom 9:12
“Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ,
a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà,
ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ,
èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.”
24Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́. 25Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau. 26Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn.
Esau Ta Ipò Àgbà Rẹ̀
27Nígbà tí àwọn ọmọ náà dàgbà, Esau di ògbójú ọdẹ, a sì máa lọ sí oko ọdẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ilé ni ó sì máa ń sábà gbé ní tirẹ̀. 28Isaaki fẹ́ràn Esau nítorí ẹran ìgbẹ́ tí ó máa ń fún un jẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu ni Rebeka fẹ́ràn.
29Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú. 30Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.)#25:30 Edomu Èyí tí ó túmọ̀ sí “Pupa” .
31Jakọbu bá dáhùn pé, “Kọ́kọ́ gbé ipò àgbà rẹ fún mi ná.”
32Esau dá a lóhùn, ó ní, “Ebi ń pa mí kú lọ báyìí, ò ń sọ̀rọ̀ ipò àgbà, kí ni ipò àgbà fẹ́ dà fún mi?”
33Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi ná.” Esau bá búra fún Jakọbu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gbé ipò àgbà fún un.#Heb 12:16. 34Jakọbu bá fún Esau ní àkàrà ati ẹ̀bẹ ati ẹ̀fọ́. Nígbà tí Esau jẹ, tí ó mu tán, ó bá tirẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe fi ojú tẹmbẹlu ipò àgbà rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JẸNẸSISI 25: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀