JẸNẸSISI 27
27
Isaaki Súre fún Jakọbu
1Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.”
2Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi. 3Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi. 4Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.”
5Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́, 6Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀, 7pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú. 8Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ. 9Lọ sinu agbo ẹran rẹ, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ meji tí ó lọ́ràá wá, kí n fi se irú oúnjẹ aládùn tí baba yín fẹ́ràn fún un, 10o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.”
11Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára. 12Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.”
13Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.” 14Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn. 15Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. 16Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀, 17ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀.
18Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?”
19Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.”
20Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.”
21Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.” 22Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.” 23Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un. 24Ó bèèrè pé, “Ṣé ìwọ gan-an ni Esau, ọmọ mi?” Jakọbu bá dáhùn pé, “Èmi ni.”
25Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún. 26Isaaki baba rẹ̀ bá pè é ó ní, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.” 27Jakọbu bá súnmọ́ baba rẹ̀, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Baba rẹ̀ gbóòórùn aṣọ rẹ̀, ó sì súre fún un, ó ní,
“Òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí OLUWA ti bukun.
28Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀run
ati ilẹ̀ tí ó dára
ati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini.
29Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́,#Heb 11:20. #Jẹn 12:3.
kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ.
Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ,
àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́,
ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”
Esau Bẹ Isaaki fún Ìre
30Bí Isaaki ti súre fún Jakọbu tán, Jakọbu fẹ́rẹ̀ má tíì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi ti oko ọdẹ dé. 31Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.”
32Isaaki, baba rẹ̀ bi í pé, “Ìwọ ta ni?” Esau bá dá a lóhùn pé, “Èmi ọmọ rẹ ni. Èmi, Esau, àkọ́bí rẹ.”
33Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.”
34Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.”
35Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.”
36Esau bá dáhùn pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀ nítòótọ́. Ó di ìgbà keji tí yóo fi èrú gba ohun tíí ṣe tèmi. Ó ti kọ́kọ́ gba ipò àgbà lọ́wọ́ mi, ó tún wá jí ìre mi gbà lọ.” Esau bá bèèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Ṣé o kò wá fi ẹyọ ìre kan pamọ́ fún mi ni?”#Jẹn 25:29-34.
37Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”
38Esau bẹ̀rẹ̀ sí bẹ baba rẹ̀ pé, “Ṣé ìre kan ṣoṣo ni o ní lẹ́nu ni, baba mi? Áà! Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau bá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.#Heb 12:17.
39Nígbà náà ni Isaaki, baba rẹ̀, dá a lóhùn, ó ní,
“Níbi tí ilẹ̀ kò ti lọ́ràá ni o óo máa gbé,
níbi tí kò sí ìrì ọ̀run.
40Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè,#Heb 11:20. #Jẹn 36:8; 2 A. Ọba 8:20.
arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn,
ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà,
o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”
41Nítorí irú ìre tí baba wọn sú fún Esau yìí ni Esau ṣe kórìíra Jakọbu. Esau dá ara rẹ̀ lọ́kàn le ó ní, “Ìgbà mélòó ni ó kù tí baba wa yóo fi kú? Bí ó bá ti kú ni n óo pa Jakọbu, arakunrin mi.”
42Ṣugbọn wọ́n sọ ohun tí Esau, àkọ́bí Rebeka ń wí fún Rebeka ìyá rẹ̀. Rebeka bá ranṣẹ pe Jakọbu, ó wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀, Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pẹlu ìpinnu láti pa ọ́.#Ọgb 10:10. 43Nítorí náà, ọmọ mi, gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, wá gbéra kí o sálọ bá Labani, arakunrin mi, ní Harani. 44Kí o sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ títí tí inú tí ń bí arakunrin rẹ yóo fi rọ̀, 45tí inú rẹ̀ yóo yọ́, tí yóo sì gbàgbé ohun tí o ti ṣe sí i, n óo wá ranṣẹ pè ọ́ pada nígbà náà. Mo ha gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ ẹ̀yin mejeeji lọ́jọ́ kan náà bí?”
Isaaki Rán Jakọbu Lọ sọ́dọ̀ Labani
46Rebeka sọ fún Isaaki, ó ní, “Ọ̀rọ̀ àwọn obinrin Hiti wọnyi mú kí ayé sú mi. Bí Jakọbu bá lọ fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin ará Hiti, irú àwọn obinrin ilẹ̀ yìí, irú ire wo ni ó tún kù fún mi láyé mọ́?”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JẸNẸSISI 27: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: