HAGAI 1

1
OLUWA pàṣẹ láti tún Tẹmpili Kọ́
1Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Hagai sí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa.#Ẹsr 4:24–5:2; 6:14
2OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Àwọn eniyan wọnyi ní, kò tíì tó àkókò láti tún Tẹmpili kọ́.” 3Nítorí náà ni OLUWA ṣe rán wolii Hagai sí wọn ó ní, 4“Ẹ̀yin eniyan mi, ṣé àkókò nìyí láti máa gbé inú ilé tiyín tí ẹ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí Tẹmpili wà ní àlàpà? 5Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín: 6Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí. 7Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 8Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.
9“Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀. 10Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ. 11Mo mú ọ̀gbẹlẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ati sórí àwọn òkè, ati oko ọkà, ati ọgbà àjàrà ati ọgbà igi olifi. Bẹ́ẹ̀ náà ló kan gbogbo ohun tí ń hù lórí ilẹ̀, ati eniyan ati ẹran ọ̀sìn, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan.”
Àwọn Eniyan náà gbọ́ràn sí Àṣẹ OLUWA
12Ni Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa, ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù bá gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun wọn lẹ́nu, wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wolii Hagai, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wọn ti rán an; wọ́n sì bẹ̀rù OLUWA. 13Ni Hagai, òjíṣẹ́ OLUWA, bá jẹ́ iṣẹ́ tí OLUWA rán an sí àwọn eniyan náà pé òun OLUWA ní òun wà pẹlu wọn. 14OLUWA bá fi ìtara rẹ̀ sí ọkàn Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí ọkàn Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wọn. 15Ọjọ́ kẹrinlelogun, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HAGAI 1: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀