AISAYA 1
1
1Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda. #a 2A. Ọba 15:1-7; 2Kron 26:1-23; b 2A. Ọba 15:32-38; 2Kron 27:1-9; d 2A. Ọba 16:1-20; 2Kron 28:1-27; e 2A. Ọba 18:1–20:21; 2Kron 29:1–32:33
OLUWA Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Wí
2Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run,
sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé
Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀
Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ,
tí mo tọ́ wọn dàgbà tán,
ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi.
3Mààlúù mọ olówó rẹ̀;
kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un;
ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan,
òye kò yé àwọn eniyan mi.”
4Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,
àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ,
ìran oníṣẹ́ ibi;
àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́!
Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀,
wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹli
wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i.
5Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni,
àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù?
Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò,
gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì.
6Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín,
kò síbìkan tí ó gbádùn.
Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀.
Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.
7Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro,
wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.
Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.
Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀.
8Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà,
ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí;
ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì.
9Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni,
à bá rí bí i Sodomu,
à bá sì dàbí Gomora. #Jẹn 19:24; Rom 9:29
10Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,
ẹ̀yin ìjòyè Sodomu:
Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa,
ẹ̀yin ará Gomora
11OLUWA ní,
“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?
Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;
bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.
N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.
12Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,
ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.
13Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;
ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.
Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.
Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.
14Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.
Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,
n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi. #Amos 5:21-22
15“Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,
n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.
Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbadura
n kò ní gbọ́;
nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,
16Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká.
Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́.
Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.
17Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere.
Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́.
Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́.
Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”
18OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.
Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná,
yóo di funfun bí ẹfun.
Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì,
yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.
19Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn,
ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà.
20Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun;
idà ni yóo run yín.”
Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.
Ìlú tí Ó kún fún Ẹ̀ṣẹ̀
21Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó,
ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn.
22Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.
Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.
23Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;
gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.
Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.
24Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:
“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,
n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.
25Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,
n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.
N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.
26N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.
Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,
lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”
27A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;
a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.
28Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,
àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.
29Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ.
Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn.
30Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé,
ati bí ọgbà tí kò lómi.
31Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀,
iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná.
Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀,
kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010