AISAYA 12

12
Orin Ọpẹ́
1O óo sọ ní ọjọ́ náà pé,
“N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA,
nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi,
inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu.
2Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi,#Eks 15:2; O. Daf 118:14
n óo gbẹ́kẹ̀lé e
ẹ̀rù kò sì ní bà mí,
nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi,
òun sì ni Olùgbàlà mi.”
3Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlà
bí ẹni pọn omi láti inú kànga.
4Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé,
“Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA,
ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,
ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;
ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga.
5Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA
nítorí ó ṣe nǹkan tí ó lógo,
jẹ́ kí èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé.
6Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni,
ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni,
nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹli
tí ó wà láàrin yín.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 12: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀