AISAYA 14
14
Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn
1OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu.
2Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára.
Ọba Babiloni ní Isà Òkú
3Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe, 4ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé:
“Agbára aninilára ti pin
ìpayà ojoojumọ ti dópin.
5OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi,
ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí
6tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró,
tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè,
tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́.
7Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafia
wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀.
8Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín;
àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé,
‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀,
kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’
9“Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé.
Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ,
àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn,
Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.
10Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé,
‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà.
Ẹ ti dàbí i wa.
11A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú.
Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lórí
àwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’
12“Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run,#Ifi 8:10; 9:1
ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀!
Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀,
ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí.
13Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé,
‘N óo gòkè dé ọ̀run,
n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run;
n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan,
ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.
14N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run,
n óo wá dàbí Olodumare.’
15Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú,#Mat 11:23; Luk 10:15
sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
16“Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ,
wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé,
‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí,
tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì;
17ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,
tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run,
ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’
18Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọn
olukuluku ninu ibojì tirẹ̀.
19Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ,
bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé,
tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù;
tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun;
àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta,
bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.
20A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù,
nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run,
o sì ti pa àwọn eniyan rẹ.
Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae!
21Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ run
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn,
kí wọn má baà tún gbógun dìde,
kí wọn gba gbogbo ayé kan,
kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.”
Ọlọrun Yóo Pa Babiloni Run
22OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn. 23N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ọlọrun Yóo Pa Àwọn Ará Asiria Run
24OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní,
“Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí;
ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ.
25Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi;
n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.
Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi,
ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí.
26Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí,
mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.”
27OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu;#Ais 10:15-34; Nah 1:1–3:19; Sef 2:13-15
ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?
Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣe
ta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?
Ọlọrun Yóo Pa Àwọn Ará Filistini Run
28Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:#2A. Ọba 16:20; 2Kron 28:27
29Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,
ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;
nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,
ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.
30Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ,
aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu.
Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ,
a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.
31Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè,#Jer 47:1-7; Ẹsr 25:15-17; Joẹl 3:4-8; Amo 1:1-8; Sef 2:4-7; Sek 9:5-7
kí ìwọ ìlú sì figbe ta.
Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì
nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá,
kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn
tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn.
32Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini?
A óo sọ fún wọn pé,
“OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀
àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀
yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 14: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010