AISAYA 22

22
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu
1Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran:
Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ,
2ẹ̀yin tí ìlú yín kún fún ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá?
Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun.
3Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ,
láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn.
Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà.
4Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé,
“Ẹ ṣíjú kúrò lára mi
ẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò,
ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún,
nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.”
5Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,
ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran.
Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀
ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá.
6Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká,
pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin,
àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn.
7Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogun
àwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè;
8ó ti tú aṣọ lára Juda.
Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó, 9ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ. 10Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe. 11Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá.
12Ní ọjọ́ náà,
OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé,
kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀,
kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
13Ṣugbọn dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀,#1 Kọr 15:32
ẹ̀ ń yọ̀, inú yín ń dùn.
Ẹ̀ ń pa mààlúù, ẹ̀ ń pa aguntan,
ẹ̀ ń jẹ ẹran, ẹ̀ ń mu ọtí waini.
Ẹ̀ ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu!
Nítorí pé lọ́la ni a óo kú.”
14OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé:
“A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yín
títí tí ẹ óo fi kú.”
Ìkìlọ̀ fún Ṣebina
15OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé: 16‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta? 17Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá. 18Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ. 19N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’
20“Ní ọjọ́ náà, n óo pe Eliakimu, iranṣẹ mi, ọmọ Hilikaya. 21N óo gbé aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n óo sì dì í ní àmùrè rẹ; n óo gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́, yóo sì di baba fún àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda. 22N óo fi í ṣe alákòóso ilé Dafidi. Ìlẹ̀kùn tí ó bá ṣí, kò ní sí ẹni tí yóo lè tì í; èyí tí ó bá tì, kò ní sí ẹni tí yóo lè ṣí i. 23N óo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí èèkàn tí a kàn mọ́ ilẹ̀ tí ó le, yóo di ìtẹ́ iyì fún ilé baba rẹ̀.#Ifi 3:7
24“Gbogbo ẹbí rẹ̀ ní agboolé baba rẹ̀ yóo di ẹrú rẹ̀, ati àwọn ọmọ ati àwọn ohun èlò, láti orí ife ìmumi, títí kan ìgò ọtí.”
25OLUWA àwọn ọmọ-ogun ní, “Ní ọjọ́ náà, èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gbọningbọnin yóo yọ, wọn yóo gé e, yóo sì wó lulẹ̀, ẹrù tí wọn fi kọ́ lórí rẹ̀ yóo sì já dànù.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 22: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀