AISAYA 3
3
Ìdàrúdàpọ̀ Ní Jerusalẹmu
1Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo mú
gbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò,
ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda.
Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé,
ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀.
2Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò,
pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii,
àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà;
3àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá,
àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn.
4Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn,
àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn.
5Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn,
olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀,
àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn.
Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà,
àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.
6Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀,
ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé,
“Ìwọ ní aṣọ ìlékè,
nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa;
gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.”
7Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé,
“Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe.
N kò ní oúnjẹ nílé
bẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ.
Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.”
8Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀,
Juda sì ti ṣubú.
Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA,
wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀.
9Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n;
wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu:
Wọn kò fi bò rárá.
Ègbé ni fún wọn,
nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn.
10Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọn
nítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn.
11Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,
kò ní dára fún wọn.
Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
12Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!
Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;
àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.
Ẹ̀yin eniyan mi,
àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,
wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.
OLUWA Dá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Lẹ́jọ́
13OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;
ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́
14OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀
siwaju ìtẹ́ ìdájọ́,
yóo sọ fún wọn pé;
“Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run,
ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín.
15Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,
tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”
Ìkìlọ̀ fún Àwọn Obinrin Jerusalẹmu
16OLUWA ní,
“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,
bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;
wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.
Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dún
bí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.
17OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;
yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”
18Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn; 19ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn. 20Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn, 21òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú, 22ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò 23ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá.
24Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara,
okùn yóo wà dípò ọ̀já;
orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́,
aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye.
Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà.
25Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín,
àwọn akikanju yín yóo kú sógun.
26Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu.
Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò,
tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010