AISAYA 37
37
Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Aisaya
(2A. Ọba 19:1-7)
1Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì wọ inú ilé OLUWA lọ. 2Ó rán Eliakimu tí ń ṣàkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ilé ẹjọ́ ati àwọn àgbààgbà alufaa, wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi. 3Wọ́n jíṣẹ́ fún un, wọ́n ní, “Hesekaya ní kí á sọ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ òní, ọjọ́ ìyà, ati ọjọ́ ẹ̀sín. Ọmọ ń mú aboyún, ó dé orí ìkúnlẹ̀, ṣugbọn kò sí agbára láti bíi. 4Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ”
5Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya, 6Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní:
‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́
tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
7Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀,
yóo gbọ́ ìròyìn èké kan,
yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.
Nígbà tí ó bá dé ilé
n óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ”
Àwọn Ará Asiria Tún Halẹ̀ Lẹẹkeji
8Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun.
9Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní: 10“Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. 11Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni? 12Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari? 13Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?”
Adura Hesekaya
14Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA, 15Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní: 16“Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé.#Eks 25:22 17Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà. 18Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, 19ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run. 20Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni OLUWA.”
Aisaya Ranṣẹ Pada sí Ọba
21Aisaya ọmọ Amosi bá ranṣẹ sí Hesekaya, pé OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí pé Hesekaya ti gbadura sí òun nípa Senakeribu ọba Asiria, 22ohun tí OLUWA sọ nípa rẹ̀ ni pé:
“Sioni bu ẹnu àtẹ́ lù ọ́, Senakeribu,
ó fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà,
Jerusalẹmu ń yọ ṣùtì sí ọ.
23Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà?
Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga?
Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí?
24O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,
o ní,
‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ,
mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni.
Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,
ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀.
Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀,
ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ.
25Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn.
Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’
26“Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́,
ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii?
Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀,
pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀,
kí ó di òkítì àlàpà.
27Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọn
má ní agbára mọ́,
kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà.
Kí wọ́n dàbí ewé inú oko
ati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù
bí koríko tí ó hù lórí òrùlé,
tíí gbẹ kí ó tó dàgbà.
28“Mo mọ ìjókòó rẹ.
Mo mọ ìjáde ati ìwọlé rẹ,
ati inú tí ò ń bá mi bí.
29Nítorí pé ò ń bá mi bínú,
mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ,
n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú,
n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu,
n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá.
30“Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀. 31Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso. 32Àwọn eniyan yóo ṣẹ́kù tí yóo wá láti Jerusalẹmu àwọn tí wọn yóo sá àsálà yóo wá láti orí òkè Sioni. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí.
33“Nítorí náà, ohun tí OLUWA wí nípa ọba Asiria ni pé, ‘Kò ní wọ inú ìlú yìí, kò sì ní ta ọfà sí i. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò ní kó apata wọ inú rẹ̀. Wọn kò sì ní dó tì í. 34Ọ̀nà tí ọba Asiria gbà wá ni yóo gbà pada lọ, kò ní fi ẹsẹ̀ kan inú ìlú yìí. 35N óo dáàbò bo ìlú yìí, n óo sì gbà á sílẹ̀ nítorí tèmi ati nítorí Dafidi iranṣẹ mi.’ ”
36Angẹli OLUWA bá lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) ninu wọn. Nígbà tí wọn jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ òkú kún ilẹ̀ lọ kítikìti. 37Senakeribu ọba Asiria bá pada sílé, ó ń lọ gbé ìlú Ninefe.
38Ní ọjọ́ kan, ó lọ bọ Nisiroku, oriṣa rẹ̀, àwọn meji ninu àwọn ọmọ rẹ̀: Adirameleki ati Ṣareseri, sì fi idà gún un pa, wọ́n bá sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 37: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: