AISAYA 40:6-7

AISAYA 40:6-7 YCE

Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!” Mo bá bèèrè pé, “Igbe kí ni kí n ké?” Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan, gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀ nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú. Dájúdájú koríko ni eniyan.