AISAYA 44

44
Ọlọrun kanṣoṣo ni OLUWA
1OLUWA ní:
“Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi
ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi.
2Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,
ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,
tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:
Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,
Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.
3“N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ
n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.
N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,
n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,
4wọn óo rúwé bíi koríko inú omi#Ais 48:12; Ifi 1:8,17; 2:8; 22:13
àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn.
5“Ẹnìkan yóo wí pé,
‘OLUWA ló ni mí.’
Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu.
Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀
yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.”
6Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,
OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,
“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;
lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.
7Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀
kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi.
Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,
kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa.
8Má bẹ̀rù, má sì fòyà.
Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́,
mo ti kéde rẹ̀,
ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi:
Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi?
Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”
A fi Ìwà Ìbọ̀rìṣà ṣẹ̀sín
9Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n. 10Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè? 11Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀.
12Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́.
13Agbẹ́gilére a ta okùn sára igi, a fi ẹfun fa ìlà sí i, a fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, a sì gbẹ́ ẹ bí eniyan: ẹwà rẹ̀ a dàbí ti eniyan, wọn a sì kọ́lé fún un. 14Ó lè gé igi kedari lulẹ̀, tabi kí ó gbin igi Sipirẹsi, tabi igi Oaku, kí ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó. Ó sì lè gbin igi kedari kan, omi òjò a sì mú kí ó dàgbà. 15Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un. 16Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.” 17Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”#Ọgb 13:11-19
18Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn. 19Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?” 20Kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń pe eérú ní oúnjẹ. Èrò ẹ̀tàn ti ṣì í lọ́nà, kò sì lè gba ara rẹ̀ kalẹ̀ tabi kí ó bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ irọ́ kọ́ ni ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi yìí?”
OLUWA, Ẹlẹ́dàá ati Olùgbàlà
21Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi,
nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli.
Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́,
n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli.
22Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma,
mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu.
Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada.
23Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é.
Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀.
Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀,
nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada,
yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli.
24Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí,
ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún.
Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo.
Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run,
tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́,
25èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán,#1 Kọr 1:20
tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀.
Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n po
mo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀.
26Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi,
tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ,
èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé,
‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’
tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé,
‘A óo tún odi yín mọ,
n óo sì tún yín kọ́.’
27Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ!
n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’
28èmi tí mo sọ fún Kirusi pé:#2Kron 36:23; Ẹsr 1:2
‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’
tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé:
‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’
tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé,
‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 44: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀