AISAYA 7
7
Aisaya Jíṣẹ́ OLUWA fún Ahasi Ọba
1Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.#2A. Ọba 16:15; 2Kron 28:5-6 2Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó.
3OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀. 4Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín. 5Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé, 6‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’
7“Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀. 8Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́. 9Ṣebí Samaria ni olú-ìlú Efuraimu, Ọmọ Remalaya sì ni olórí Samaria. Bí ẹ kò bá gbàgbọ́ ẹ kò ní fẹsẹ̀ múlẹ̀.”
Àmì Imanuẹli
10OLUWA tún sọ fún Ahasi pé: 11“Bèèrè àmì tí ó bá wù ọ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ–ìbáà jìn bí isà òkú, tabi kí ó ga bí ojú ọ̀run.” 12Ṣugbọn Ahasi dáhùn, ó ní: “Èmi kò ní bèèrè nǹkankan, n kò ní dán OLUWA wò.” 13Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu? 14Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli. 15Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ. 16Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀.#Mat 1:23
17“OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀.
18“Ní ọjọ́ náà OLUWA yóo súfèé pe àwọn eṣinṣin tí ó wà ní orísun gbogbo odò Ijipti ati àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Asiria. 19Gbogbo wọn yóo sì rọ́ wá sí ààrin àwọn àfonífojì, ati gbogbo kọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ ní ààrin àpáta, ati ara gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún ati gbogbo pápá.
20“Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo mú ọba Asiria wá láti òdìkejì odò. Yóo lò ó bí abẹ ìfárí, yóo fi fá irun orí ati irun ẹsẹ̀ dànù, ati gbogbo irùngbọ̀n pàápàá.
21“Ní ọjọ́ náà, eniyan yóo máa sin ẹyọ mààlúù kékeré kan ati aguntan meji péré, 22wàrà tí yóo máa rí fún yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wàrà ati oyin ni yóo máa fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nítorí pé wàrà ati oyin ni àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà yóo máa jẹ.
23“Ní ọjọ́ náà, gbogbo ibi tí ẹgbẹrun ìtàkùn àjàrà wà, tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹrun ṣekeli fadaka, yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. 24Àwọn eniyan yóo kó ọrun ati ọfà wá sibẹ, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. 25Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
AISAYA 7: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: