JAKỌBU 2
2
Ẹ Má Ṣe Ojuṣaaju
1Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju. 2Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá wọ àwùjọ yín, tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tí ń dán, tí talaka kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí; 3ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.” 4Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú.
5Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. 6Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! 7Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín!
8Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.”#Lef 19:18 9Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju, ẹ di arúfin, ati ẹni ìbáwí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí arúfin. 10Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin. 11Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin.#a Eks 20:14; Diut 5:18; b Eks 20:13; Diut 5:17 12Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira. 13Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́.
Igbagbọ ati Iṣẹ́
14Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là? 15Bí arakunrin kan tabi arabinrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí kò jẹun fún odidi ọjọ́ kan, 16tí ẹnìkan ninu yín wá sọ fún un pé, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun yóo pèsè aṣọ ati oúnjẹ fún ọ,” ṣugbọn tí kò fún olúwarẹ̀ ní ohun tí ó nílò, anfaani wo ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣe? 17Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni.
18Ṣugbọn ẹnìkan lè sọ pé, “Ìwọ ní igbagbọ, èmi ní iṣẹ́.” Fi igbagbọ rẹ hàn mí láìsí iṣẹ́, èmi óo fi igbagbọ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ mi. 19Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn. 20Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú? 21Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ?#Jẹn 22:1-14; Sir 44:19-21; 1 Makab 2:52 22O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé. 23Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun.#a Jẹn 15:6 b 2Kron 20:7; Ais 41:8 24Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan?
25Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ?#Joṣ 2:1-21
26Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JAKỌBU 2: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: