ÀWỌN ADÁJỌ́ 21
21
Àwọn Ẹ̀yà Bẹnjamini Fẹ́ Iyawo
1Àwọn ọmọ Israẹli ti búra nígbà tí wọ́n wà ní Misipa pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní fi ọmọ rẹ̀ fún ará Bẹnjamini.” 2Àwọn eniyan bá wá sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó níwájú Ọlọrun títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì sọkún gidigidi. 3Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?”
4Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níbẹ̀. 5Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.” 6Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí káàánú àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini arakunrin wọn, wọ́n ní, “Ẹ̀yà Israẹli dín kan lónìí. 7Báwo ni a óo ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù; nítorí pé a ti fi OLUWA búra pé a kò ní fi àwọn ọmọbinrin wa fún wọn?”
8Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà. 9Nítorí pé nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ, ẹnikẹ́ni láti inú àwọn tí ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi kò sí níbẹ̀. 10Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn. 11Ohun tí ẹ ó ṣe nìyí: gbogbo ọkunrin wọn ati gbogbo obinrin tí ó bá ti mọ ọkunrin, pípa ni kí ẹ pa wọ́n.” 12Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.
13Ni ìjọ eniyan bá ranṣẹ sí àwọn ará Bẹnjamini tí wọ́n wà níbi àpáta Rimoni, pé ìjà ti parí, alaafia sì ti dé. 14Nígbà náà ni àwọn ará Bẹnjamini tó pada wá, àwọn ọmọ Israẹli sì fún wọn ní àwọn obinrin tí wọ́n mú láàyè ninu àwọn obinrin Jabeṣi Gileadi, ṣugbọn àwọn obinrin náà kò kárí wọn.
15Àánú àwọn ọmọ Bẹnjamini bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé OLUWA ti dín ọ̀kan kù ninu ẹ̀yà Israẹli. 16Àwọn àgbààgbà ìjọ eniyan náà bá bèèrè pé, “Níbo ni a óo ti rí aya fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, níwọ̀n ìgbà tí a ti pa àwọn obinrin ẹ̀yà Bẹnjamini run.” 17Wọ́n bá dáhùn pé, “Àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn ara Bẹnjamini gbọdọ̀ ní ogún tiwọn, kí odidi ẹ̀yà kan má baà parun patapata ní Israẹli. 18Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.”
19Wọ́n bá pinnu pé, “Ọdọọdún ni a máa ń ṣe àjọ̀dún OLUWA ní Ṣilo, tí ó wà ní apá àríwá Bẹtẹli, ní apá ìlà oòrùn òpópó ọ̀nà tí ó lọ láti Bẹtẹli sí Ṣekemu, ní apá gúsù Lebona.” 20Wọ́n bá fún àwọn ọkunrin Bẹnjamini láṣẹ pé, “Ẹ lọ ba ní ibùba ninu ọgbà àjàrà, 21kí ẹ máa ṣọ́ àwọn ọmọbinrin Ṣilo bí wọ́n bá wá jó; ẹ jáde láti inú ọgbà àjàrà, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ki iyawo kọ̀ọ̀kan mọ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọbinrin Ṣilo, kí ẹ sì gbé wọn sá lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini. 22Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ”
23Àwọn ará Bẹnjamini bá ṣe bí wọ́n ti sọ fún wọn. Olukuluku wọn gbé obinrin kọ̀ọ̀kan sá lọ ninu àwọn tí wọ́n wá jó, gbogbo wọn sì pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ìlú wọn kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. 24Àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò níbẹ̀, gbogbo wọ́n sì pada sí ilẹ̀ wọn, olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀, sí ààrin ẹbí rẹ̀.
25Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.#A. Ada 17:6
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ADÁJỌ́ 21: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: