JEREMAYA 3
3
Israẹli Alaiṣododo
1OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀,
tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ,
tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn,
ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada?
Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́?
Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́;
ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi?
2Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká,
ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé?
Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà,
bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀.
Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́.
3Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀,
tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ.
Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó,
ojú kò sì tì yín.
4Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé,
‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
5Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni?
Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’
Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀,
ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.”#2A. Ọba 22:1–23:30; 2Kron 34:1–35:27
Israẹli ati Juda Gbọdọ̀ Ronupiwada
6OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù? 7Mo rò pé yóo pada tọ̀ mí wá, lẹ́yìn tí ó bá ṣe àgbèrè rẹ̀ tán ni; ṣugbọn kò pada; Juda arabinrin rẹ̀, alaiṣootọ sì rí i, 8ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè. 9Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́. 10Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
11Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀. 12Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé:
‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí.
N kò ní máa bínú lọ títí lae.
13Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,
ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.
O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,
lábẹ́ gbogbo igi tútù;
o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’
14“Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni. 15N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín. 16Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀ 17Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́. 18Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.”
Ìbọ̀rìṣà Àwọn Eniyan Ọlọrun
19OLUWA ní,
“Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi,
tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára,
kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù,
láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.
Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ,
ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.
20Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
21A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga,
ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni.
Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn;
wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn.
22Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ,
n óo mú aiṣootọ yín kúrò.
“Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ,
nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa.
23Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè,
ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀;
dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
24Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìí
ti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run:
ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn,
àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin.
25Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá,
nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa;
àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa,
a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: