JEREMAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Wolii Jeremaya ṣiṣẹ́ ìyìn rere rẹ̀ láàrin ẹgbẹta ọdún ó lé bíi ọdún mẹẹdọgbọn sí ẹgbẹta ọdún ó dín bíi ọdún mẹẹdogun kí á tó bí OLUWA wa (625 sí 585 B.C.) Ní àkókò rẹ̀, ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan nípa irú àjálù ńlá tí yóo dé bá wọn nítorí ìwà ìbọ̀rìṣà ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìran tí ó rí sí wọn ṣẹ nígbà ayé rẹ̀, Nebukadinesari ọba Babiloni ko àwọn ará Jerusalẹmu lẹ́rú, wọ́n dáná sun Jerusalẹmu ati Tẹmpili, wọ́n sì kó ọba Juda ati ọpọlọpọ eniyan lẹ́rú. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọn yóo dá wọn sílẹ̀ lóko ẹrú, wọn yóo dá wọn pada wálé, orílẹ̀-èdè náà yóo sì pada bọ̀ sípò.
A lè pín Ìwé Jeremaya sí ọ̀nà bíi marun-un: (1) Ìpè Jeremaya (2) Àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí orílẹ̀-èdè Juda ati àwọn olórí ní àkókò ìjọba Josaya, Jehoiakimu, Jehoiakini ati Sedekaya. (3) Àwọn àkọsílẹ̀ Baruku, tí ó jẹ́ akọ̀wé Jeremaya, pẹlu ọpọlọpọ àkọsílẹ̀ ìran ati ìṣẹ̀lẹ̀ pataki pataki tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wolii Jeremaya. (4) Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. (5) Ìtàn ìṣubú Jerusalẹmu ati bí wọn ṣe kó àwọn ará orílẹ̀-èdè náà lọ sí oko ẹrú ní Babiloni, ni wọ́n fi parí ìwé yìí.
Jeremaya jẹ́ onífura eniyan, tí ó nífẹ̀ẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí kì í sìí fẹ́ dájọ́ ìjìyà fún àwọn eniyan rẹ̀. Ó mẹ́nuba àwọn ìṣòro tí ó dojú kọ nítorí pípè tí Ọlọrun pè é láti wá ṣe iṣẹ́ wolii. Ọ̀rọ̀ OLUWA ń jó o lọ́kàn bí iná, nítorí náà, kò lè ṣàì jíṣẹ́ tí OLUWA rán an.
Ọpọlọpọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí ni ó tọ́ka sí àkókò ọjọ́ iwájú, tí majẹmu tuntun yóo wáyé, tí àwọn eniyan Ọlọrun yóo máa tẹ̀lé, wọn kò ní retí, pé kí olùkọ́ kan máa kọ́ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oókan àyà wọn ni wọn yóo fi majẹmu náà sí. Ìgbé-ayé ìgbà náà yóo yàtọ̀ sí àkókò tí Jeremaya ati àwọn eniyan rẹ̀ ń kojú ìṣòro (31.31-34).
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìpè Jeremaya 1:1-19
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ní àkókò ìjọba Josaya, Jehoiakimu, Jehoiakini ati Sedekaya 2:1–25:38
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ nígbà ayé Jeremaya 26:1–45:5
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìjìyà àwọn orílẹ̀ èdè 46:1–51:64
Ìṣubú Jerusalẹmu 52:1-34

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀