JOHANU 19

19
1Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án. 2Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì, 3wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí.
4Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.” 5Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”
6Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”
Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.”
7Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.”
8Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. 9Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?”
Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. 10Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?”
11Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”#Ọgb 6:3
12Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.”
13Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu. 14Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Àjọ̀dún Ìrékọjá ni ọjọ́ náà. Ó tó nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Pilatu sọ fún àwọn Juu pé, “Ọba yín nìyí!”
15Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!”
Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?”
Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.”
16Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.
Wọ́n Kan Jesu Mọ́ Agbelebu
(Mat 27:32-44; Mak 15:21-32; Luk 23:26-43)
Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. 17Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu. 18Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin. 19Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.” 20Pupọ ninu àwọn Juu ni ó ka àkọlé náà ní èdè Heberu ati ti Latini ati ti Giriki. 21Àwọn olórí alufaa àwọn Juu sọ fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ ọ́ pé ‘Ọba àwọn Juu,’ ṣugbọn kọ ọ́ báyìí: ‘Ó ní: èmi ni ọba àwọn Juu.’ ”
22Ṣugbọn Pilatu dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ ná.”
23Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀. 24Wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Ẹ má jẹ́ kí á ya á, gègé ni kí ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ láti mọ ti ẹni tí yóo jẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé,
“Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,
wọ́n ṣẹ́ gègé lórí ẹ̀wù mi.”
Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ-ogun sì ṣe.#O. Daf 22:18
25Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu. 26Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”
27Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀.
Ikú Jesu
(Mat 27:45-56; Mak 15:33-41; Luk 23:44-49)
28Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”#O. Daf 69:21; 22:15
29Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu. 30Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!”
Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.
Ọmọ-ogun Kan Fi Ọ̀kọ̀ Gún Jesu Lẹ́gbẹ̀ẹ́
31Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà. 32Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun. 33Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun. 34Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde. 35(Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.) 36Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.”#Eks 12:46; Nọm 9:12; O. Daf 34:20 37Ìwé Mímọ́ tún wí níbòmíràn pé, “Wọn yóo wo ẹni tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún.”#Sak 12:10; Ifi 1:7
Ìsìnkú Jesu
(Mat 27:57-61; Mak 15:42-47; Luk 23:50-56)
38Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e. 39Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu.#Joh 3:1-2 40Wọ́n fi òróró yìí tọ́jú òkú Jesu, wọ́n bá wé e ní aṣọ-ọ̀gbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìsìnkú àwọn Juu. 41Ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti kan Jesu mọ́ agbelebu. Ibojì titun kán wà ninu ọgbà náà, wọn kò ì tíì sin òkú kankan sinu rẹ̀ rí. 42Wọ́n tẹ́ òkú Jesu sibẹ, nítorí ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn Juu ni, ati pé ibojì náà súnmọ́ tòsí.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOHANU 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀