JOBU 11

11
1Sofari ará Naama dáhùn pé,
2“Ǹjẹ́ ó dára kí eniyan sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ kalẹ̀ báyìí kí ó má sì ìdáhùn?
Àbí, ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lè mú kí á dá eniyan láre?
3Ṣé o rò pé ìsọkúsọ rẹ lè pa eniyan lẹ́nu mọ́ ni?
Tabi pé bí o bá ń ṣe ẹlẹ́yà ẹnikẹ́ni kò lè dójútì ọ́?
4Nítorí o sọ pé ẹ̀kọ́ rẹ tọ̀nà,
ati pé ẹni mímọ́ ni ọ́ lójú Ọlọrun.
5Ọlọrun ìbá ya ẹnu rẹ̀,
kí ó sọ̀rọ̀ sí ọ.
6Kì bá jẹ́ fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́,
nítorí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ.
Mọ̀ dájú pé ìyà tí Ọlọrun fi jẹ ọ́
kò to nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
7“Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun?
Tabi kí o tọpinpin Olodumare?
8Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i?
Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀?
9Ó gùn ju ayé lọ,
Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ.
10Tí ó bá ń kọjá lọ, tí ó sì ti eniyan mọ́lé,
tí ó pe olúwarẹ̀ lẹ́jọ́,
ta ló lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò?
11Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán,
ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀,
kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀?
12Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan,
kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n.
13“Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́,
o óo lè nawọ́ sí i.
14Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́,
má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ.
15Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi;
o óo wà láìléwu,
o kò sì ní bẹ̀rù.
16O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ,
nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀,
yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.
17Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;
òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀.
18Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí,
a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.
19O óo sùn, láìsí ìdágìrì,
ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ.
20Àwọn ẹni ibi óo pòfo;
gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálà
ni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú,
ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀