JOBU 19
19
1Jobu bá dáhùn, ó ní,
2“Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó,
tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́?
3Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbà
ojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí?
4Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀,
ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà?
5Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ,
tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi,
6ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi,
tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró,
ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn;
mo pariwo, pariwo,
ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́.
8Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá,
ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn.
9Ó bọ́ ògo mi kúrò,
ó sì gba adé orí mi.
10Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà,
ó sì ti parí fún mi,
ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu.
11Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná,
ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀.
12Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ,
wọ́n dó tì mí,
wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká.
13“Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi,
àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi.
14Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀.
15Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi.
Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò,
wọ́n ń wò mí bí àjèjì.
16Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn,
bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́.
17Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi,
mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi.
18Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi;
bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi.
19Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá,
àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.
20Mo rù kan egungun,
agbára káká ni mo fi sá àsálà.
21Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,
nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!
22Ọlọrun ń lépa mi,
ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!
Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?#Sir 6:8
23“À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!
Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!
24Kí á fi kálàmú irin ati òjé
kọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.
25Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,
ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,
26lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́,
ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.
27Fúnra mi ni n óo rí i,
ojú ara mi ni n óo sì fi rí i,
kì í ṣe ti ẹlòmíràn.
“Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi!
28Bí ẹ bá wí pé, ‘Báwo ni a óo ṣe lépa rẹ̀!’
Nítorí pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí,
29ṣugbọn, ẹ bẹ̀rù idà,
nítorí pé ìrúnú níí fa kí á fi idà pa eniyan,
kí ẹ lè mọ̀ dájú pé ìdájọ́ ń bẹ.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 19: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010