JOBU 3
3
Jobu Ráhùn sí Ọlọrun
1Nígbà tí ó yá, Jobu bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ ìbí ara rẹ̀ bú.
2Ó ní:
3“Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi,
ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi.
4Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri!
Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí,
kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́.
5Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu,
ati òkùnkùn biribiri.
Kí ìkùukùu ṣíji bò ó,
kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.
6Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri,
kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́
tí ó wà ninu ọdún,
kí á má sì ṣe kà á kún
àwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù.
7Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo,
kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́.
8Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún,
àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè.
9Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn,
kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo,
kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́;
10nítorí pé kò sé inú ìyá mi
nígbà tí ó fẹ́ bí mi,
bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi.#Sir 23:14
11“Kí ló dé tí n kò kú
nígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi,
tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi?
12Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀?
Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú?
13Ǹ bá ti dùbúlẹ̀,
ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́;
ǹ bá ti sùn,
ǹ bá sì ti máa sinmi
14pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn,
àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn;
15tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà,
tí fadaka sì kún ilé wọn.
16Tabi kí n rí bí ọmọ
tí a bí ní ọjọ́ àìpé,
tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé.
17Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́,
tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi.
18Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn,
wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́.
19Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀,
àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn.#Jer 20:14-18
20“Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀
fún ẹni tí ń kérora,
tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́;
21tí ó ń wá ikú,
ṣugbọn tí kò rí;
tí ó ń wá ikú lójú mejeeji
ju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ?
22Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọ
bí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin.
23Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀
fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú;
ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́?
24Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi,
ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi.
25Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi,
ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.
26N kò ní alaafia,
bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí,
n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.”#Ifi 9:6
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOBU 3: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010