JOBU 35

35
1Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,
2“Jobu, ṣé o rò pé ó tọ̀nà,
kí o máa sọ pé, ‘Ọ̀nà mi tọ́ níwájú Ọlọrun?’
3Kí o tún máa bèèrè pé, ‘Anfaani wo ni mo ní?
Tabi kí ni mo fi sàn ju ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ?’
4N óo dá ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lóhùn.
5Gbójú sókè kí o wo ojú ọ̀run,
ati àwọn ìkùukùu tí ó wà lókè.
6Bí o bá dẹ́ṣẹ̀, kò ṣe Ọlọrun ní àìrójú,
bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá pọ̀, kò jámọ́ nǹkankan fún un.
7Bí o bá jẹ́ olódodo,
kí ni ó dà fún Ọlọrun,
tabi kí ni ó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ?
8Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára,
àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún.#Job 22:2-3
9“Àwọn eniyan ń kígbe nítorí ọpọlọpọ ìnira,
wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́,
nítorí àwọn alágbára ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
10Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó bèèrè pé,
‘Níbo ni Ọlọrun Ẹlẹ́dàá mi wà,
tíí fún ni ní orin ayọ̀ lóru,
11ẹni tí ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ju àwọn ẹranko lọ,
Ó sì fún wa ní ọgbọ́n ju àwọn ẹyẹ lọ?’
12Wọ́n kígbe níbẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lóhùn,
nítorí ìgbéraga àwọn eniyan burúkú.
13Dájúdájú Ọlọrun kì í gbọ́ igbe asán,
Olodumare kò tilẹ̀ náání rẹ̀.
14Kí á má tilẹ̀ sọ ti ìwọ Jobu, tí o sọ pé
o kò rí i,
ati pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀,
o sì ń dúró dè é!
15Ṣugbọn nisinsinyii, nítorí pé inú kì í bí i kí ó jẹ eniyan níyà,
bẹ́ẹ̀ ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ kún lọ títí.
16Jobu kàn ń la ẹnu,
ó sì ń sọ̀rọ̀ lásán ni.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀, ṣugbọn kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 35: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀