JONA 2
2
Adura Jona
1Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà,
2ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA,
ó sì dá mi lóhùn,
mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi.
3Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun,
omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀;
ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi.
4Nígbà náà ni mo sọ pé,
‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ;
báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’
5Omi bò mí mọ́lẹ̀,
ibú omi yí mi ká,
koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí.
6Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun,
àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí.
Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi,
o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.
7Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ,
mo gbadura sí ìwọ OLUWA,
o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ.
8Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀,
wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́.
9Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́,
n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi.
Ti OLUWA ni ìgbàlà!”
10OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JONA 2: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010