LUKU 24:1-53

LUKU 24:1-53 YCE

Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibojì, wọ́n mú òróró olóòórùn dídùn tí wọ́n ti tọ́jú lọ́wọ́. Wọ́n rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa. Bí wọ́n ti dúró tí wọn kò mọ ohun tí wọn yóo ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin meji kan bá yọ sí wọn, wọ́n wọ aṣọ dídán. Ẹ̀rù ba àwọn obinrin náà, wọ́n bá dojúbolẹ̀. Àwọn ọkunrin náà wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú? Kò sí níhìn-ín; ó ti jí dìde. Ẹ ranti bí ó tí sọ fun yín nígbà tí ó wà ní Galili pé, ‘Dandan ni kí á fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan burúkú lọ́wọ́, kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu, ati pé kí ó jí dìde ní ọjọ́ kẹta.’ ” Wọ́n wá ranti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá kúrò ní ibojì náà, wọ́n pada lọ sọ gbogbo nǹkan tí wọ́n rí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati gbogbo àwọn yòókù. Maria Magidaleni, ati Joana, ati Maria ìyá Jakọbu ati gbogbo àwọn yòókù tí ó bá wọn lọ, ni wọ́n sọ nǹkan wọnyi fún àwọn aposteli. Ṣugbọn bíi ìsọkúsọ ni gbogbo ọ̀rọ̀ yìí rí létí wọn. Wọn kò gba ohun tí àwọn obinrin náà sọ gbọ́. [ Ṣugbọn Peteru dìde, ó sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí ó yọjú wo inú rẹ̀, aṣọ funfun tí wọ́n fi wé òkú nìkan ni ó rí. Ó bá pada sí ilé, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.] Ní ọjọ́ kan náà, àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń lọ sí abúlé kan tí ó ń jẹ́ Imausi. Ó tó bí ibùsọ̀ meje sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń bá ara wọn jíròrò lórí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ. Ṣugbọn ó dàbí ẹni pé a dì wọ́n lójú, wọn kò mọ̀ pé òun ni. Ó bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ bí ẹ ti ń rìn bọ̀? Kí ló dé tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀?” Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kilopasi dá a lóhùn pé, “Ṣé àlejò ni ọ́ ní Jerusalẹmu ni, tí o kò fi mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní ààrin bí ọjọ́ mélòó kan yìí?” Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa ati àwọn ìjòyè wa fà á fún ìdájọ́ ikú, wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì, wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.” Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ! Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.” Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ abúlé tí wọn ń lọ, Jesu ṣe bí ẹni pé ó fẹ́ máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀ ẹ́ pupọ pé, “Dúró lọ́dọ̀ wa, ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ ti ṣú.” Ni ó bá bá wọn wọlé, ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Nígbà tí ó ń bá wọn jẹun, ó mú burẹdi, ó súre sí i, ó bù ú, ó bá fi fún wọn. Ojú wọn bá là; wọ́n wá mọ̀ pé Jesu ni. Ó bá rá mọ́ wọn lójú. Wọ́n wá ń bá ara wọn sọ pé, “Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú wa lọ́kàn bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà, ati bí ó ti ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ fún wa!” Wọ́n bá dìde lẹsẹkẹsẹ, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati àwọn tí ó wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n péjọ sí, àwọn ni wọ́n wá sọ fún wọn pé, “Oluwa ti jí dìde nítòótọ́, ó ti fara han Simoni.” Ni àwọn náà wá ròyìn ìrírí wọn ní ojú ọ̀nà ati bí wọ́n ti ṣe mọ̀ ọ́n nígbà tí ó bu burẹdi. Bí wọ́n ti ń sọ àwọn nǹkan wọnyi lọ́wọ́, Jesu alára bá dúró láàrin wọn. Ó ní, “Alaafia fun yín.” Wọ́n ta gìrì, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n ṣebí iwin ni. Ṣugbọn ó ní, “Kí ni ń bà yín lẹ́rù. Kí ni ó ń mú iyè meji wá sí ọkàn yín? Ẹ wo ọwọ́ mi ati ẹsẹ̀ mi, kí ẹ rí i pé èmi gan-an ni. Ẹ fọwọ́ kàn mí kí ẹ rí i, nítorí iwin kò ní ẹran-ara ati egungun bí ẹ ti rí i pé mo ní.” Nígbà tí ó wí báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọn. Nígbà tí wọn kò gbàgbọ́ sibẹ nítorí pé ó yà wọ́n lẹ́nu ati pé wọn kò rí bí ó ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ẹ ní nǹkan jíjẹ níhìn-ín?” Wọ́n bá bù ninu ẹja díndín fún un. Ó bá gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn. Ó bá sọ fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ tí mo sọ fun yín nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìyí, pé dandan ni kí ohun gbogbo tí a sọ nípa mi kí ó ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ wọ́n sílẹ̀ ninu ìwé Òfin Mose ati ninu ìwé àwọn wolii ati ninu ìwé Orin Dafidi.” Ó bá là wọ́n lọ́yẹ kí Ìwé Mímọ́ lè yé wọn. Ó wá tún sọ fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Mesaya gbọdọ̀ jìyà, kí ó sì jí dìde kúrò ninu òkú ní ọjọ́ kẹta. Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọnyi. N óo rán ẹ̀bùn tí Baba mi ṣe ìlérí sí orí yín. Ṣugbọn ẹ dúró ninu ìlú yìí títí agbára láti òkè wá yóo fi sọ̀kalẹ̀ sórí yín.” Jesu bá kó wọn jáde lọ sí Bẹtani. Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn. Bí ó ti ń súre fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni a bá fi gbé e lọ sí ọ̀run. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn júbà rẹ̀, wọ́n bá fi ọpọlọpọ ayọ̀ pada lọ sí Jerusalẹmu. Inú Tẹmpili ni wọ́n ń wà nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun.