MATIU 21

21
Jesu Fi Ẹ̀yẹ Wọ Jerusalẹmu
(Mak 11:1-11; Luk 19:28-38; Joh 12:12-19)
1Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé Bẹtifage ní Òkè Olifi, Jesu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji lọ ṣiwaju. 2Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó wà ní ọ̀kánkán yín yìí. Bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, pẹlu ọmọ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ mú wọn wá fún mi. 3Bí ẹnìkan bá bi yín ní nǹkankan, ẹ dá a lóhùn pé, ‘Oluwa#21:3 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní gbolohun Oluwa wọn dípò Oluwa. nílò wọn.’ Lẹsẹkẹsẹ wọn yóo jẹ́ kí ẹ mú wọn wá.”
4Kí ọ̀rọ̀ tí wolii nì sọ lè ṣẹ pé,
5“Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé,#Sak 9:9
Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ;
pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.”
6Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. 7Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn. 8Ọ̀pọ̀ ninu àwọn eniyan tẹ́ aṣọ wọn sọ́nà; àwọn mìíràn ya ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ wọn sọ́nà. 9Àwọn èrò tí ń lọ níwájú, ati àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wá ń kígbe pé,
“Hosana fún Ọmọ Dafidi,
olùbùkún ni ẹni tí ó wá lórúkọ Oluwa.
Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run.”#O. Daf 118:25-26
10Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?”
11Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.”
Jesu Fòpin sí Ìwà Ìbàjẹ́ ninu Tẹmpili
(Mak 11:15-19; Luk 19:45-48; Joh 2:13-22)
12Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú. 13Ó sọ fún wọn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi jẹ́,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí.”#Ais 56:7 Jer 7:11
14Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili, ó sì wò wọ́n sàn. 15Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin rí àwọn ohun ìyanu tí Jesu ṣe, tí wọ́n tún gbọ́ bí àwọn ọmọde ti ń kígbe ninu Tẹmpili pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi,” inú wọn ru. 16Wọ́n sọ fún un pé, “O kò gbọ́ ohun tí àwọn wọnyi ń wí ni?”
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́. Ẹ kò tíì kà á pé, ‘Lẹ́nu àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ni ìwọ ti gba ìyìn pípé?’ ”#O. Daf 8:2
17Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì jáde kúrò lọ sí Bẹtani. Níbẹ̀ ni ó gbé sùn.
Jesu Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Gégùn-ún
(Mak 11:12-14, 20-24)
18Lówùúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ó ti ń pada lọ sinu ìlú, ebi ń pa á. 19Bí ó ti rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́nà, ó yà lọ sí ìdí rẹ̀, ṣugbọn, kò rí nǹkankan lórí rẹ̀ àfi kìkì ewé. Ó bá sọ fún un pé, “O kò ní so mọ́ laelae.” Lẹsẹkẹsẹ ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà bá gbẹ!
20Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ lẹsẹkẹsẹ.”
21Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.#Mat 17:20; 1 Kọr 13:2 22Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ninu adura, bí ẹ bá gbàgbọ́, ẹ óo rí i gbà.”
Ìjiyàn Lórí Agbára Jesu
(Mak 11:27-33; Luk 20:1-8)
23Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?”
24Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, èmi náà yóo wá sọ irú agbára tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi. 25Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, báwo ló ti jẹ́: ṣé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?”
Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn, wọ́n ń wí pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ 26Bí a bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ a bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí gbogbo eniyan gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.” 27Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”
Ó bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fun yín.”
Òwe nípa Àwọn Ọmọ Meji
28Ó wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa èyí? Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Ó lọ sọ́dọ̀ ekinni, ó sọ fún un pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà mi lónìí.’ 29Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘N kò ní lọ.’ Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó ronupiwada, ó bá lọ. 30Ọkunrin náà lọ sọ́dọ̀ ọmọ keji, ó sọ fún un bí ó ti sọ fún ekinni. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘Ó dára, mo gbọ́, Baba!’ Ṣugbọn kò lọ. 31Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?”
Wọ́n ní, “Ekinni ni.”
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun. 32Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.”
Òwe nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà
(Mak 12:1-12; Luk 20:9-19)#Luk 3:12; 7:29-30
33Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀.#Ais 5:1-2 34Nígbà tí ó tó àkókò ìkórè, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ sí àwọn alágbàro náà láti gba ìpín tirẹ̀ wá ninu èso rẹ̀. 35Ṣugbọn àwọn alágbàro náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n na àwọn kan, wọ́n pa àwọn kan, wọ́n sọ àwọn mìíràn ní òkúta. 36Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn. 37Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’ 38Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ 39Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.
40“Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?”
41Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.”
42Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé,#O. Daf 118:22-23.
‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀,
òun ni ó di pataki ní igun ilé.
Iṣẹ́ Oluwa ni èyí,
ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’
43“Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [ 44Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”]
45Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí. 46Wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí àwọn eniyan gbà á bíi wolii.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 21: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀