MAKU 10

10
Ẹ̀kọ́ Nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn
(Mat 19:1-12; Luk 16:18)
1Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.
2Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni.
3Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?”
4Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda pé kí ọkọ kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún iyawo rẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́.”#Diut 24:1-4; Mat 5:31
5Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Nítorí oríkunkun yín ni Mose fi kọ òfin yìí. 6Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn.#Jẹn 1:27; 5:2 7Nítorí èyí ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóo wá fi ara mọ́ iyawo rẹ̀; 8àwọn mejeeji yóo wá di ọ̀kan. Wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́ bíkòṣe ọ̀kan.#Jẹn 2:24 9Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà á.”
10Nígbà tí wọ́n pada wọ inú ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í nípa ọ̀rọ̀ náà. 11Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí ó gbé ẹlòmíràn ní iyawo, ó ṣe àgbèrè sí iyawo rẹ̀ àkọ́kọ́. 12Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.”#Mat 5:32; 1 Kọr 7:10-11
Jesu Bukun Àwọn Ọmọde
(Mat 19:13-15; Luk 18:15-17)
13Àwọn kan gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. 14Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. 15Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.”#Mat 18:3 16Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn.
Ọkunrin Ọlọrọ̀ kan
(Mat 19:16-30; Luk 18:18-30)
17Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”
18Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan. 19Ṣé o mọ àwọn òfin: má paniyan, má ṣe àgbèrè, má jalè, má jẹ́rìí èké, má rẹ́nijẹ, bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ?”#a Eks 20:13; Diut 5:17; b Eks 20:14; Diut 5:18; d Eks 20:15; Diut 5:19; e Eks 20:16; Diut 5:20 ẹ Eks 20:12; Diut 5:16.
20Ọkunrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin ni mo ti ń pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́.”
21Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.” 22Ṣugbọn ojú ọkunrin náà fàro nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó bá jáde lọ pẹlu ìbànújẹ́, nítorí pé ọrọ̀ tí ó ní pọ̀.
23Jesu bá wo ọ̀tún, ó wo òsì, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Yóo ṣòro pupọ fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”
24Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí gbolohun yìí. Ṣugbọn Jesu tún wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọde, yóo ṣòro pupọ láti wọ ìjọba Ọlọrun! 25Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”
26Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pupọ. Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo là?”
27Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.”
28Peteru bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé, “Wò ó ná, a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ láti tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”
29Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, 30tí kò ní rí ilé, arakunrin ati arabinrin, ìyá ati ọmọ, ati ilẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ìlọ́po ní ìgbà ìsinsìnyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu inúnibíni ni, yóo sì tún rí ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀. 31Ṣugbọn ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ẹni iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo wá di ẹni iwájú.”#Mat 20:16; Luk 13:30
Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta
(Mat 20:17-19; Luk 18:31-34)
32Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, tí wọn ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, Jesu ṣáájú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹ̀rù sì ba àwọn eniyan tí wọ́n tẹ̀lé e. Ó bá tún pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun fún wọn. 33Ó ní, “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́. Wọn yóo dá a lẹ́bi ikú, wọn yóo sì fi lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. 34Wọn yóo fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n yóo tutọ́ sí i lára, wọn yóo nà án, wọn yóo sì pa á. Ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.”
Jakọbu ati Johanu Bèèrè Ipò Ọlá
(Mat 20:20-28)
35Nígbà náà ni Jakọbu ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ kí o ṣe ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.”
36Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”
37Wọ́n ní, “Gbà fún wa pé, nígbà tí ó bá di ìgbà ìgúnwà rẹ, kí ọ̀kan ninu wa jókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ, kí ẹnìkejì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ.”
38Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ṣé ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu, tabi kí ojú yín rí irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí?”#Luk 12:50
39Wọ́n wí fún un pé, “Àwa lè ṣe é.”
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ninu irú ife ìrora tí n óo mu ẹ̀yin náà yóo mu, irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí, tiyín náà yóo sì rí i. 40Ṣugbọn ní ti jíjókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ẹ̀gbẹ́ òsì mi, kì í ṣe tèmi láti fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí Ọlọrun ti pèsè wọn sílẹ̀ fún.”
41Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn sí Jakọbu ati Johanu. 42Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn, 43ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín;#Luk 22:25-26 44ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín.#Mat 23:1; Mak 9:35; Luk 22:26 45Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”
Jesu Wo Batimiu Afọ́jú Sàn
(Mat 20:29-34; Luk 18:35-43)
46Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe. 47Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!”
48Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.”
49Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.”
Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”
50Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.
51Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”
Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”
52Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.”
Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MAKU 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀